Ọgbẹni Ọladiran Ọladokun ni oludasilẹ ati adari ẹgbẹ awọn ọdọ atọmọ ilu Igangan (Igangan Development Advocates), nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ. Ọladiran ba akọroyin ALAROYE, FAITH ADEBỌLA, sọrọ lori foonu nipa rogbodiyan to waye laipẹ yii, to mu ki wọn le Seriki Fulani atawọn Fulani kan kuro niluu naa.
ALAROYE: A gbọ pe Seriki Fulani ti wọn le lọ n’Igangan sọ pe oun tun fẹẹ pada wa ti wọn ba foun laaye, bawo lẹ ṣe ri eyi si?
ỌLADIRAN: Ohun ti mo mọ ni pe gbogbo ilu Igangan, koda gbogbo Ibarapa patapata, Igangan, Tapa, Ayetẹ, Idere, Igbo-Ọra, Lanlatẹ ati Eruwa, gbogbo wa lẹnu wa ko lasiko yii, ohun kan naa si ni ipinnu wa pe, kaka ti Seriki Fulani, Salihu AbdulKadir yii yoo ba fi pada waa tun maa gbe ilu yii, ti igba inira yoo tun pada de, gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un, gbogbo okun ati agbara to ba ṣẹku fawọn ni awọn yoo sa lati dena iru nnkan bẹẹ.
Ẹni to ba ti wa ninu igbekun ati oko-ẹru yoo mọ pe nnkan buruku gbaa ni. Niwọnba asiko ti Seriki ti lọ yii, ẹ beere pe eeyan meloo ni maaluu tun ti jẹ oko ẹ, eeyan meloo ni wọn tun ṣa ladaa pa, eeyan meloo ni wọn da ni gbese tabi to sare janna-janna pada wale latoko? Ṣe iyẹn la waa tun fẹẹ pada si ni? Ọlọrun o ni i jẹ ka tun rohun to maa mu iru Seriki yẹn wọ ilu yii wa mọ, mo si mọ poun naa ko jẹ gbiyanju ẹ.
Alaroye: Olori awọn Fulani naa sọ pe mọto mọkanla ni wọn jo, awọn eeyan oun meje lo ku, toun ṣi wa meji ninu oku wọn, ṣe loootọ ni?
ỌLADIRAN: Irọ ni. Niṣe ni Seriki n ṣe oju aye, o n sọ iyẹn lati le mu kawọn eeyan le maa ba a kẹdun, ki wọn maa ṣaanu ẹ, ki wọn le ro pe boya wọn ti fiya jẹ ẹ. O si tun n sọ iyẹn lati da ogun silẹ, kawọn araalu ẹ le ro pe niṣe ni wọn dẹyẹ sọmọ awọn, boya ki wọn le waa gbeja ẹ, tabi ki wọn gbẹsan.
Lati bii ogun ọdun ti Seriki ti wa niluu yii, toun naa si mọ ohun to n ṣẹlẹ, to ri bawọn Fulani ṣe n han wa leemọ, ẹ bi i lere, njẹ igba kan ṣoṣo pere tiẹ wa to ri ẹni kan tọka si pe ara awọn Fulani ọbayejẹ ree, eleyii ki i ṣe ara wa, ẹ mu un. Ko ṣẹlẹ ri, boya ko tiẹ fẹyọ kan jofin. Ko waye ri.
Ẹ tun bi i leere pe bawo lo ṣe jẹ gbogbo igba ti wọn ba mu wọn, oun lo maa n dide, to si maa n lo gbogbo agbara ẹ, gbogbo ipo ẹ, lati ri i pe wọn tu wọn silẹ, ko tiẹ ni i jẹ ki wọn sun oorun ọjọ kan latimọle. Ti wọn ba si ti tu awọn araabi yii silẹ, wọn aa pada sinu oko lati tun lọọ ṣe aburu to ju ti tẹlẹ lọ ni, iyẹn lo ba wa de ibi ta a de yii.
Alaroye: Ṣe ọhun tẹ ẹ n sọ ni pe loootọ ni Seriki yii n ṣe onigbọwọ ati apapin pẹlu awọn Fulani ọbayejẹ yii?
ỌLADIRAN: Ti ki i baa ṣe ohun to ṣẹlẹ si mi ni, n ba sọ pe boya wọn n ṣe abumọ nipa rẹ ni. Oko bii eeka mẹfa lemi atawọn ẹgbọn mi da lọdun kan, oko ọhun wa nikọja Ketepe, ka too de Odo Eleere tan, nitosi Apodun, apa ibẹ ni wọn pa Dokita Aborode si lọjọsi. Ẹgẹ (paki) la gbin sinu ẹ, o si ṣe daadaa. Bawọn Fulani yii ṣe lọọ fi maaluu jẹ oko naa nirọlẹ ọjọ kan niyẹn, lẹyin ta a ti kuro loko. Bi mọ ṣe gbọ, mo kawọ leri ni, n lawọn tiru ẹ ti ṣẹlẹ si ba n sọ fun wa pe awọn Fulani naa ṣi tun maa pada wa, pe wọn ṣi maa waa pari iwọnba to ku. Mo kọkọ ro pe irọ ni, n lemi atawọn ẹṣọ Fijilante meloo kan ba lọ laaarọ ọjọ keji, a lugọ sitosi oko naa, mo mu foonu mi dani, pe boya a maa le ri ẹni kan gba mu, ki n si yaworan ohun to n ṣẹlẹ gẹgẹ bii ẹri. Si iyalẹnu mi, njẹ ẹ mọ pe wọn pada wa loootọ, wọn o ri wa, ṣugbọn rekete lawa n wo wọn, bẹẹ ni mo n ya fidio ati fọto wọn bi wọn ṣe ṣe oko olowo iyebiye naa baṣubaṣu. Ika gidi lawọn araabi yii o.
Nigba ta a pe ọlọpaa, a tọpasẹ wọn de Sudu (agọ Fulani), ta a mu ẹni to ko maaluu waa jẹko yẹn, ẹsẹkẹsẹ ni ẹni to ni maaluu yẹn ti pe Seriki AbdulKadir yii lori aago, kia lo ti dide, toun naa ti pe Seriki Igo, iyẹn Seriki awọn Bororo, ẹya keji awọn Fulani, n la ba ko si ọrọ yii, ni wọn ba bẹrẹ si i ba wa fa a, wọn ni dandan ni ka tu Fulani ta a mu sahaamọ naa silẹ. A taku mọ wọn lọwọ, ṣugbọn nigba ti yooo fi di irọlẹ, wọn pada fi afurasi ọdaran naa silẹ.
Wọn bẹrẹ si i bẹ wa pẹlu ẹgbẹrun mẹwaa naira, tẹn taosan, fun oko eeka mẹfa, kẹ ẹ maa wo iwọsi ati iya ti wọn fi jẹ wa, ara aje o tiẹ ta wọn pin-in, niṣe ni wọn tun n da ara wọn lare, pe ṣe awọn ko ṣee to ni, lori tẹn taosan. Nigba ta o gba, Seriki yii pe ọmọ ẹ kan, Umaru, lọọya loun, niṣe ni wọn bẹrẹ si i halẹ mọ wa pe awọn maa ba wa fa a gidi ta o ba ti gba lẹrọ.
Igba to ya, ọga ọlọpaa gan-an lo tun n bẹ wa pe ka fẹjọ silẹ, ka gba iye ti wọn lawọn maa fun wa, ẹgbẹrun lọna aadọrin ni wọn pada san, bẹẹ owo paki ọkọ kan nigba yẹn ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un lọ, a si le mu to ọkọ mẹfa ninu oko ti wọn bajẹ ọhun.
Titi ta a fi gba kamu lori ẹjọ naa, ẹ o le gbọ ki Seriki ba Fulani kan wi pe o ṣe ohun ti ko daa. Oun lo maa n jẹ oniduuro fun wọn, oun lo n mọ bi wọn ṣe maa tu wọn silẹ. Tori ẹ, ko sohun ti wọn fẹsun ẹ kan ti mo le jiyan, ṣe ẹ si mọ pe o ti pẹ niluu naa, o ti mọ ọpọ nnkan nipa oko ati ilẹ wa.
Alaroye: Ti ijọba ba sọ pe ki wọn pada siluu nkọ?
ỌLADIRAN: Iyẹn o ṣoro, ijọba naa lo maa ba a wa aaye sileejọba. Wọn le fun un nilẹ ki wọn tiẹ kọle fun un ni Government House, n’Ibadan, tabi ilẹ to jẹ tijọba. A o binu siyẹn. Ṣugbọn lori ilẹ tiwa, laarin awa araalu nibi, o maa ṣoro gidi.
Alaroye: Ki lẹ ri si ipade tawọn gomina ilẹ Yoruba lọọ ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn onimaaluu Miyetti Allah l’Ondo lọsẹ to kọja yii?
Mo gboriyin fun Gomina Akeredolu fun aṣẹ to pa pe kawọn Fulani kuro ninu igbo ọba, bi wọn si ṣe ni ki wọn maa forukọ silẹ naa daa.
Ka maa sọ ọ, ka maa la a, ki i ṣe gbogbo Fulani lo buru. Titi di bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, awọn Fulani wa niluu Igangan, bẹ ẹ ba de adugbo AUD, tabi ile Babamogba, lọ si Oke-Atapo, ẹ maa ba awọn Fulani ni Gaa wọn nibẹ, awọn mi-in ni agbo maaluu ninu wọn, wọn si ti wa pẹlu wa tipẹ ta o ri wọn nidii ibajẹ tabi aburu kan, ko sẹni to fọwọ kan wọn, wara lawọn iyawo wọn n ta. Tori naa, ọrọ ilẹ yii ki i ṣe ti ikorira tabi ti ẹlẹyamẹya.
Ṣugbọn akiyesi ti mo ṣe ni pe ijọba apapọ gan-an lo n ki ẹlẹyamẹya bọ ọrọ yii. Tẹ ẹ ba kiyesi i, Akeredolu ko ti i paṣẹ ọhun tan tijọba ti sare fesi, ti ileeṣẹ Aarẹ ti n sọ pe awọn o fara mọ aṣẹ yẹn. Wọn o tiẹ duro yiiri ẹ wo rara, pẹlu itara ni wọn fi fesi, itara ẹya, wọn o wo ti pe Government Reserved Forest la n sọrọ nipa ẹ yii. Teeyan ba pe nnkan ni “Reserved”, to si jẹ tijọba, ṣebi nnkan to gbọdọ ni ọwọ, to si maa leto ninu ni. Ileeṣẹ aarẹ ko wo iyẹn, ọrọ pe ki wọn ma sọ awọn Fulani lẹnu ni wọn fi fesi pada. Iru nnkan bayii lo n ki awọn Miyetti Allah atawọn Fulani darandaran laya, tori wọn n ri atilẹyin ijọba ni wọn fi sọ ara wọn di aṣẹ-ma-lu, ẹran ọba. Awọn Miyẹtti Allah ti gba pe awọn kọja ofin, ohun ti wọn ba ṣe, aṣegbe ni, nigba tawọn adari wa ti gbe ẹya bori ofin, o ti bo ofin mọlẹ. Ara ohun to jẹ ki nnkan bajẹ de ibi to de yii niyẹn.
Amọran temi, to yẹ ki gomina wa nipinlẹ Ọyọ di mu bayii ni pe, yatọ si awọn ipinnu ti wọn ti ṣe lati tubọ mu ki eto aabo gbopọn si i, o yẹ ki wọn ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ti yoo maa ta ijọba lolobo. Wọn tun gbọdọ mọ bi wọn ṣe fẹẹ ṣakoso kiko ibọn wọlu. Iru ilu Igangan yii, ati agbegbe Ibarapa, ọna to wọ ibẹ pọ, o si sun mọ ẹnubode orileede mi-in, aimọye ọna lawọn ọdaran le gba wọlu ti wọn aa si ko nnkan ija wọle. O yẹ kijọba ṣiṣẹ lori iyẹn.
O tun yẹ ki awọn agbofinro maa ṣakiyesi igbokegbodo awọn ajoji wọnyi latigbadegba, ki wọn si tete maa gbe igbesẹ. Bii apẹẹrẹ, to ba jẹ nigba ti wọn pa Aborode ni gomina ti gbe iru igbesẹ to ṣẹṣẹ fẹẹ gbe yii ni, to ti da awọn Amọtẹkun siluu, soko, boya ọrọ yii iba ma de ibi to de yii. Ko yẹ ki wọn maa ki ọrọ oṣelu bọ ẹdun ọkan araalu, ki wọn maa ro pe awọn ti ko fẹ kijọba Makinde ṣaṣeyọri ni wọn n le Fulani kuro. Ki Gomina wa ma ṣe ri awọn ọdọ ilu Igangan bii ọlọtẹ tabi alatako. Ọpọ igba ni ijọba ki i mọ iyatọ laarin ẹni to n ta ko wọn, ṣugbọn ti ki i ṣe ọlọtẹ, awa ọdọ ilu Igangan ki i ṣe ọlọtẹ ijọba, Gomina wa ni Seyi Makinde, a gbaruku ti wọn nigba ti wọn n polongo ibo, awa la si dibo yan wọn sipo. Niṣe ni ki wọn jẹ ki ọrọ wa ta leti wọn, ki wọn ma ro pe boya awọn oloṣelu kan lo fẹẹ maa ti wa ṣiṣẹ, ko ri bẹẹ rara.
Alaroye: Ki ni iha ti Ọba Aṣigangan kọ si gbogbo ọrọ yii?
ỌLADIRAN: Kabiyesi wa, Ọba Lasisi Adeoye, wa pẹlu awọn ara ilu, wọn si ṣepade pẹlu awọn kan, bemi o tiẹ si nibẹ. Ṣugbọn ọba ti jade fẹnu ara wọn sọ pe latigba yii lọ, awọn o fara mọ ohun tawọn Fulani n ṣe wọnyi. Ṣe ẹ mọ pe wọn ti dagba, awa ọdọ la ni ọjọ-ọla ilu, ohun tawọn le ṣe ni ki wọn ṣatilẹyin fun wa.
Tẹlẹtẹlẹ, nigbakan ri, gbogbo wa la fẹhonu han si kabiyesi pe wọn o tiẹ ṣe bii ẹni pe wọn ri iya to n jẹ araalu, to si da bii ẹni pe wọn fẹẹ fì si ọdọ Seriki nigba yẹn. Ṣugbọn iyẹn ti kọja, ọba wa wa lẹyin wa digbi lasiko yii.
Alaroye: Ki lẹ tun ro pe ijọba le ṣe lafikun si i?
ỌLADIRAN: Seriki o parọ pe awọn oniluu kan wa ti wọn le maa ṣonigbọwọ fun awọn Fulani apaayan naa. Oun naa lo mọ awọn wọnyẹn, oun naa lo n lo wọn. Ṣe bi iku ile o ba si pa ni, wọn ni t’ode ko le pa ni. Ara ibi ti ijọba tun ni lati tanna wo niyẹn. Bi mo ṣẹ sọ lẹẹkan, ki i ṣe gbogbo Fulani ni ko daa. Bẹẹ naa lo ṣe jẹ pe kan-n-da inu irẹsi wa ninu awọn Yoruba naa, ti wọn le maa gbabọde. Ṣugbọn Seriki to sọ ọ naa lo le ran awọn agbofinro lọwọ. Bi ijọba ba tete bẹrẹ iwadii, ti wọn fimu finlẹ daadaa, wọn aa le mọ awọn ọmọ oniluu ti wọn n ṣe wọlewọde pẹlu Seriki yii, tabi ti wọn jọ da nnkan pọ, wọn aa si le gbe igbesẹ to yẹ lori wọn.
Ohun mi-in tun ni pe kijọba ṣiṣẹ lori awọn ile akọku ati iṣẹ aṣepati (abandoned projects) to wa kaakiri awọn igberiko ati igbo agbegbe yii. Apẹẹrẹ kan ni ti iṣẹ Adamond to wa lọna Eehu, iyẹn lọna to lọ si abule Abidioki, ka too maa lọ si Ẹlẹkọọkan. Ileewosan ni wọn fẹẹ fi kọ tẹlẹ, ki wọn too gbagbe ẹ latọdun yii wa. Bawọn Fulani ṣe sọ ibẹ di ibuba wọn niyẹn. Igba ti Sunday Igboho wa laṣiiri too to, igba yẹn lawọn eeyan too laya lati de ibẹ, nigba tawọn Fulani ri wọn, wọn sa lọ ni. Oriṣiiriṣii nnkan ija ti wọn fi n ṣọṣẹ lo kun ibẹ. Iru awọn ile akọku, awoku, ti wọn sọ di ibuba wọnyi wa kaakiri awọn igbo ati oko wa, o yẹ kijọba ṣe nnkan nipa ẹ.
Nnkan mi-in ni ti awọn igbo agbegbe Ibarapa. Ilẹ Ibarapa gbooro gidi, titi lọọ fi de Ijio ati Iwere-Ile. Awọn kan ti wọn ti ṣọdẹ lọ sinu awọn igbo yii maa n royin bi wọn ṣe n ba ori ati ẹya ara eeyan pade lawọn ibi kan, to jẹ awọn Fulani ti sọ ibẹ ni ibuba wọn. Kijọba ṣeto fawọn Amọtẹkun atawọn ọdẹ lati fọ awọn igbo wọnyi.
Alaroye: Ki ni ilu n ṣe lati dena boya awọn Fulani yii le fẹẹ gbẹsan?
ỌLADIRAN: Lara ẹ ni awọn igbesẹ ti gomina wa ti gbe yẹn, wọn lawọn maa fi awọn ẹṣọ Amọtẹkun bii igba (200) sọwọ si Oke-Ogun, ko yẹ kiyẹn pẹ rara.
Gẹgẹ bii ilu, ilu ti ṣofin konilegbele tiwa niluu, pe kawọn eeyan ma ṣe kọja aago mẹsan-an alẹ nita, ko le ṣee ṣe fawọn agbofinro lati ṣiṣẹ ni gbogbo oru.
Bawo ni aabo lọna oko ṣe ri lasiko yii fawọn agbẹ?
Awọn to loko etile nikan ni wọn ṣi le lọ soko wọn lasiko yii, awọn yẹn naa o si gbọdọ da lọ, wọn gbọdọ to mẹta si mẹrin, ki wọn kọwọọrin lọ ni, tori awọn Fulani buruku kan ṣi le fara pamọ sinu igbo. Ni ti awọn to loko sọna iwaju, tabi awọn ti wọn fẹẹ lọọ mu ire oko wọn, a ti sọ fun wọn pe ki kaluku ṣi ṣera ro na, ki eruku rogbodiyan yii tubọ lọ silẹ daadaa, ifura loogun agba, oju si lalakan fi n sọ ori.
A gbagbọ pe igba ọtun ti bẹrẹ bayii, omi alaafia yoo si tubọ toro fun wa mu lagbara Ọlọrun.
CAPTION