Faith Adebọla
Tan-tan-an-tan lẹlẹkọ ọrun n powo iku niluu Ṣagamu, nijọba ibilẹ Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, bayii pẹlu bawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe n bara wọn ja, to si jọ pe wọn ti pinnu lati ba ara wọn na an tan bii owo lasiko yii, eeyan to ju ogun lọ ni wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun da ẹmi ẹ legbodo laarin alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an yii, si afẹmọju ọjọ Aje, Mọnde, oṣu yii kan naa.
ALAROYE gbọ pe bii ẹni figbalẹ pa eṣinṣin lawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Ẹiyẹ’ ati ‘Aye’ n wọle tọ ara wọn lọ, ti wọn si bẹrẹ si i fi ibọn, ada, aake ati awọn nnkan ija oloro ṣa ara wọn balẹ.
Ẹnikan to pe orukọ ara ẹ ni Wasiu Ṣobọwale, kegbajare lori ikanni X, iyẹn Tuita, pe “ẹ gba wa o, a o le sun mọ niluu Ṣagamu bayii o. Ko din ni eeyan mẹtadinlogun tiwọn ti yinbọn pa loni-in laarin wakati diẹ niluu Ṣagamu o. O ti to eeyan mẹẹẹdọgbọn laarin ọjọ meji pere, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn n pa ara wọn bẹẹ o. Nibo lawọn ijọba wa wa gan-an? Mi o le sun nigba ti mo n wo fidio bi wọn ṣe eeyan mẹfa si meje ninu yara kan ṣoṣo.”
Ọkunrin naa fi kun un pe, “ibọn to wa lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii pọ ju eyi to wa nileeṣẹ ọlọpaa lọ o.”
ALAROYE gbọ pe eyi to pọ ju lọ ninu awọn ti fi ẹjẹ rẹ yii yeepẹ yii ni wọn jẹ ọmọleewe tabi ọdọ, wọn lọpọ ninu wọn ni wọn ṣi n kawe lọwọ nileewe sẹkọndiri.
Lara awọn adugbo ti ifẹmiṣofo naa ti rinlẹ ju ni Agbọwa, lẹyinkule aafin ọba Ewusi tilu Makun, Makun, Ijagba, Ajaka, Isalẹ Ọkọ ati Sabo. Wọn niṣe lawọn eeyan naa n wọle tọ awọn ti wọn ba fura si pe ẹgbẹ okunkun wọn yatọ si tiwọn, ti wọn si n yinbọn mọ wọn.
Amọ awọn kan tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ki i ṣe kidaa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn n pa. Ẹnikan sọ pe, “fun apẹẹrẹ, wọn pa awọn akẹkọọ ileewe sẹkọndiri mẹta ti wọn lọọ gẹrun wọn lọjọ Sannde, lati mura silẹ fun iwọle pada sile-ẹkọ wọn ni Mọnde. Bi wọn ṣe n dari bọ lati ọdọ gẹrungẹrun ni wọn yinbọn mọ wọn lagbegbe Sabo.
“O da bii pe onigbajamọ to n gẹrun ni ṣọọbu naa ni wọn wa wa, a gbọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ni, amọ nigba ti wọn ko ba a ni wọn fibinu yinbọn fawọn ti wọn ri nibẹ lasiko yẹn.
Iṣẹlẹ yii buru jai o, ko tiẹ sẹni to mọ nnkan ti wọn n ja fun gan-an ti wọn fi n ṣoro bii agbọn bayii, ti wọn si waa sọ ẹmi eeyan di ẹmi eera lasan”, gẹgẹ bo ṣe wi.