Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Kọmiṣanna fun eto ẹkọ nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Dipọ Eluwọle, ti kọminu lorii bi ede Yoruba sisọ ati kikọ ṣe di nnkan eewọ lawujọ wa bayii, ti ko si sẹni to naani rẹ mọ.
O ni pupọ laluri to n ṣẹlẹ kaakiri bayii ni ko ṣẹyin bi awọn ọdọ ko ṣe ni ẹkọ nipa iwa ọmọluabi ti iran Yoruba ni eleyii ti awọn akẹkọọ maa n kọ ninu orin ati aalọ laye atijọ.
Eluwọle ṣalaye pe gbogbo nnkan yii ni Gomina Ademọla Adeleke ro papọ to fi pinnu lati pọn ẹkọ nipa ede Yoruba ni dandan nileewe alakọọbẹrẹ ati ti girama.
Lasiko to n ṣalakalẹ nipa apero lori eto-ẹkọ tijọba ipinlẹ Ọṣun fẹẹ ṣe lọsẹ to n bọ ni Eluwọle sọ pe afojusun akọkọ tijọba ni nipa ipade apero naa ni bi kikọ ede Yoruba yoo ṣe pada sinu alakalẹ eto ẹkọ.
O ṣalaye pe nibi apero naa ni wọn yoo ti ya ọjọ kan sọtọ lati sọrọ nipa akori ti wọn pe ni ‘Eto ẹkọ ipinlé Ọṣun lana-an, lonii ati lọla’, Ọba Adedokun Ọmọniyi Abọlarin, Ọrangun ti Oke-Ila ni yoo si alaga lọjọ naa.
Yatọ si ẹkọ nipa ede Yoruba, Eluwọle ni ijọba tun ti pada lati da eto ẹkọ nipa itan (History) pada sawọn ileewe ijọba kaakiri ipinlẹ Ọṣun.
O ni pupọ nnkan to ti waye kọja to jẹ arikọgbọn ni wọn maa n kọ awọn akẹkọọ laye igba ti nnkan dara, ṣugbọn ti ko si iru rẹ mọ bayii. O sọ siwaju pe loootọ ni oniruuru ipade apero ti waye kọja nipinlẹ Ọṣun, ṣugbọn bi awọn ijọba igba naa ko ṣe tẹle oniruuru imọran awọn ipade naa lo fa a ti ina eto ẹkọ fi n jo ajorẹyin nipinlẹ naa.
Alaga igbimọ eto ipade apero naa, Ọjọgbọn Oyesọji Arẹmu ṣalaye pe o ti le ni ẹgbẹrun meji (2000) aba (recommendations) ti awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ti fi ranṣẹ sigbimọ ọhun.
Arẹmu ni gbogbo nnkan ti awọn ọjọgbọn ati amoye ti wọn yoo kopa nibi apero naa ba fẹnu ko si nijọba yoo gbe igbesẹ le lori fun idagbasoke eto ẹkọ ipinlẹ Ọṣun.