Monisọla Saka
Igbakeji olori ileEgbimọ aṣofin ilẹ wa tẹlẹ, Ike Ekweremadu atiyawo ẹ, Nwanneka Beatrice Ekweremadu, ni ijọba ilẹ UK ti da lẹbi lori ọrọ kindinrin ọmọ kan ti wọn ni wọn fẹẹ lo lati fi paarọ ti ọmọ wọn ti aisan kindinrin n yọ lẹnu.
Awọn tọkọ-taya yii ati ọmọ wọn, Sonia, to fi mọ dokita to n ba wọn ṣe agbodegba, Dokita Obinna Obeta, nilee-ẹjọ ti da lẹbi lori bi wọn ṣe ṣeto irinajo ọmọkunrin kan lọ si orilẹ-ede Britain, pẹlu erongba ati lo kindinrin ọmọ naa. Lẹyin ti ile-ẹjọ Old Bailey, ti bẹrẹ igbẹjọ yii pada lati ọsẹ mẹfa sẹyin, ni wọn ti sọ pe wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni Onidaajọ Jeremy Johnson, sọ pe niṣe lawọn eeyan yii gbimọ-pọ mu ọmọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan to n ta awọn ọja pẹẹpẹẹpẹ bii ẹya ara foonu, kiri inu kẹkẹ ọmọlanke niluu Eko, wa si London, lojuna ati le lo kindinrin rẹ fọmọ tiwọn.
Latọdun to kọja ni Ekweremadu, iyawo ati ọmọ ẹ obinrin, Sonia yii ti n kawọ pọnyin rojọ niwaju ile-ẹjọ, ṣugbọn ninu igbẹjọ to waye l’Ọjọbọ Tọsidee yii, ni yoo jẹ igba akọkọ ti wọn yoo da wọn lẹbi labẹ ofin ifiniṣowo ẹru igbalode.
Tẹ o ba gbagbe, lorilẹ-ede United Kingdom ni wọn ti fi panpẹ ofin gbe Ekweremadu atiyawo ẹ lọdun to kọja, nitori bi wọn ṣe tan ọmọkunrin kan wa siluu ọhun, lojuna ati le lo kindinrin rẹ.
Ọmọkunrin yii ni wọn parọ fawọn alaṣẹ ileewosan pe ọmọ tẹgbọn-taburo loun pẹlu Sonia, ọmọ wọn, ti ara rẹ ko ya, nitori ki wọn le ba awọn dokita naa sọrọ, ki wọn gba ẹgbẹrun lọna ọgọrin (80,000 pounds), owo ilu oyinbo, ki wọn le ṣe e bii iṣẹ adani nile iwosan Royal Free Hospital, London.
Owo taṣẹrẹ kan ni wọn fi lọ ọmọ naa gẹgẹ bii owo iṣẹ ẹ, to ba le fi kindinrin rẹ silẹ fun Sonia, ti aisan kindinrin ti mu ko fi iwe akagboye ẹlẹẹkeji to waa ka lorilẹ-ede naa silẹ nileewe giga Newcastle University.
Agbefọba nile ẹjọ, Hugh Davies KC, ṣalaye fun kootu pe “bii ṣibi anumadaaro, eeyan kan ti ko ni nnkan to fẹẹ faye ẹ ṣe, ti wọn le ṣa ẹya ara ẹ ta ni Ekweremadu atiyawo ẹ, Obeta, n ṣe ọmọkunrin naa atawọn mi-in ti wọn ṣetan lati fi kindinrin wọn silẹ fọmọ ẹ. Ọrọ iṣẹ owo ni wọn ba ọmọ naa sọ, iṣesi ati ihuwasi Ekweremadu paapaa fi i han bii alailoootọ ati alabosi eeyan”.
O ni Ekweremadu fẹẹ fun eeyan lowo lati le lo kindinrin rẹ fọmọ ẹ, eeyan to jẹ pe inu iṣẹ ati iya lo n gbe, to si tun jẹ pe oun funra ẹ mọ-ọn-mọ jinna si i, bẹẹ ni ko ṣe iwadii Kankan nipa rẹ, o tun wa n gbọna ikọkọ lati ṣe gbogbo ohun to n ṣe, nitori ki orukọ ẹ gẹgẹ bii oloṣelu ma baa bajẹ.
Davies tẹsiwaju pe nnkan to fẹẹ ṣe ki i ṣe nitori alaafia ọmọ ẹ nikan, o fẹẹ fi ọmọ yẹn ṣe owo ẹru ni, iwa ọdaran si ni. O ni ko le wẹ ọrọ yii mọ kuro lara ẹ pe nitori ifẹ toun ni si Sonia, ọmọ oun ni. O ni, “Igbaye-gbadun ọmọ rẹ ko gbọdọ la ẹmi ọmọ ọlọmọ ti ailowo lọwọ n ba finra lọ”.
Ninu ọrọ tiẹ, Ekweremadu ṣalaye pe oun pe ọmọ naa lati fun ọmọ oun ni kindinrin rẹ, nitori imọran ti dokita gba oun ni pe koun ma gba kindinrin fun Sonia latinu mọlẹbi awọn.