Adewale Adeoye
Iwaju Onidaajọ Efiong Efion, tile-ẹjọ giga kan to wa niluu Eket, ipinlẹ Akwa-Ibom, ni wọn wọ Ọgbẹni Uduak Moses, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, to fipa ba awọn ọmọ ileewe girama meji sun laipẹ yii lọ. Ọjọ ori awọn akẹkọọ ọhun ko ju ọdun merinla ati mẹẹẹdogun pere lọ.
ALAROYE gbọ pe ileewe girama kan to wa niluu Efoi, nijoba ibilẹ Eket, nibi ti Moses n gbe lawọn ọmọ ọhun ti n kawe, ko too di pe o fọgbọn tan wọn ba wọn sun lakooko to ra ọja lori wọn. Ẹsun bii ogun lawọn alaṣẹ ijọba ilu naa fi kan Moses, ti wọn sọ pe o jẹ ọmọ agbegbe Efoi niwaju adajo ile-ẹjọ ọhun.
Ọkan lara awọn ọmọ to fipa ba sun sọ nile-ẹjọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, pe, ‘Emi pẹlu ọrẹ mi kan la jọ n kiri ẹran maaluu dindin ti wọn n pe ni Kanda kaakiri, olujẹjọ ri wa, lo ba ra ọja tiye rẹ jẹ ẹẹdẹgbẹrin Naira (N700) lọwọ wa, to si mu wa dele rẹ pe ka pada waa gbowo ọja wa bi a ba ti n dari pada lọ sile, iyẹn ta a ba ti taja wa tan. Nigba ta a n dari pada lọ sile la lọ sile rẹ gẹgẹ bo ṣe wi fun wa.
‘‘Nigba ta a dele rẹ, o dọgbọn tan wa wọle pe inu ile loun ti maa fun wa lowo ọja toun ra lọwọ wa, ba a ṣe wọle tan lo ti wa lu bẹẹdi rẹ, to si fipa ba awa mejeeji sun daadaa. Lẹyin to ṣetan lo ba fun wa ni idaji lara owo wa, to si tun ni ka pada waa gba owo to ku laipẹ. Moses kilọ fun wa pe a ko gbọdọ sọ ohun to ṣẹlẹ fawọn obi wa mejeeji, o ni ba a ba sọ fun wọn, tabi ẹnikẹni, oun maa pa wa danu ni. Nitori pe a ko fẹẹ ku, ni ko jẹ ka sọrọ ọhun fawon obi wa nigba ta a dele lọjọ naa.
‘‘Inu oṣu Keje, ọdun 2020, niṣẹlẹ akọkọ yii waye, nigba naa, ipele girama J.S.S.3 ni mo wa. Lẹyin ọsẹ kan ti a lọ sile rẹ lemi pẹlu ọrẹ mi yii ba tun pada lọ sile Moses, nitori to ṣi jẹ wa lowo ọja to ra lọwọ wa. Iru ọgbọn ẹwẹ to da nigba akọkọ fun wa naa lo tun da nigba keji, bo ṣe ṣe tan lo ba ni ka maa lọ sile, ko fun wa lowo gbesẹ to jẹ wa leyin to ṣe e tan. Bọrọ ọhun si ṣe wa ree lati inu oṣu Keje, ọdun 2020, di inu oṣu Kẹrin, ọdun 2021. Gbogbo igba ta a ba ti lọọ beere owo ọja wa lọwọ rẹ lo maa n dọgbọn tan wa ba sun nile rẹ, obinrin kan ti wọn jọọ n gbele lo ṣakiyesi pe wiwa wa sọdọ Moses ti digba gbogbo, oun lo lọọ fọrọ Moses to awọn obi wa leti, ko too di pe awọn obi wa gbe igbesẹ lori olujẹjọ yii’’.
Onidaajọ Efiong bu ẹnu atẹ lu olujẹjọ ni gbogbo ọna lori bo ṣe fọgbọn ẹwẹ tan awọn akẹkọọ naa, to si n ba wọn sun lọna aitọ fun aimọye oṣu, paapaa ju lọ niwọn igba ti ọkan lara awọn ẹni to fipa ba sun yii le tọka si i nile-ẹjọ. O ni pẹlu bi olujẹjọ yii ṣe bọ awọn ọmọde meji naa sihooho lẹẹkan naa, to si n ba wọn sun, o fi han gbangba pe oniranu eeyan kan ni.
Ninu idajọ rẹ, o paṣẹ pe ko maa lọ sẹwọn gbere gẹgẹ bi ijiya ẹṣẹ to ṣe naa. O ni idajọ ọhun maa jẹ ẹkọ gidi fawọn ẹlẹgbẹ rẹ gbogbo ti wọn ni i lọkan lati fipa ba ọmọde sun.