Ẹlerii ti wọn mu lori iku tọkọ-taya tawọn agbanipa sun mọle l’Abokuta ti sa lọ

Gbenga Amos, Abẹokuta

Niṣe ni awọn eeyan to gbọ pe Lekan Adekanbi, afurasi kan ṣoṣo ti wọn mu lori iku awọn tọkọ-taya nni, Kẹhinde Fatinoye ati Bukọla Fatinoye, ti awọn agbanipa lọọ ka mọ ile wọn laaarọ ọjọ ọdun tuntun, ti wọn si pa wọn, ti wọn tun dana sun oku wọn ti sa lọ mọ awọn ọlọpaa lọwọ n sọ pe njẹ ẹjọ ko ti ku s’Ake bayii, nigba ti ẹlẹrii ti fẹsẹ fẹ ẹ.

ALAROYE gbọ pe ọmokunrin naa ti sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ, wọn ko si ti i ri i di ba a ṣe n sọ yii.

A gbọ pe Lekan yii ni dẹrẹba awọn tọkọ-tiyawo ọhun, ohun si ni awọn ọlọpaa teṣan Ibara mu bii ojulowo ẹlẹrii lati le ran wọn lọwọ lori iwadii wọn gẹgẹ bi iweeroyin Daily Post ṣe ṣalaye.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni wọn ni ọmọkunrin naa ni iba n ṣe oun, n ni wọn ba yan awọn ọlọpaa meji pe ki wọn gbe e lọ si ileewosan fun itọju. Ọsibitu ọhun lo wa to fi dọgbọn bii ẹni ti itọ n gbọn, ti wọn ni o bọ si ẹyinkule lati tọ. Ṣugbọn nitori pe wọn ko fi ṣẹkẹsẹkẹ de ọmọkunrin naa lọwọ latigba ti wọn ti mu un ati nigba ti wọn gbe e lọ sile iwosan gẹgẹ ba a ṣe gbọ, kawọn agbofinro to mu un wa si ọsibitu too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Lekan ti poora mọ wọn loju bii iso, o ti sa lọ tefetefe. N lo ba ko idaamu ba awọn ọlọpaa to gbe e wa si ọsibitu ati DPO teṣan naa, CSP Bernard Ediagbonya.

ALAROYE gbọ pe oju-ẹsẹ ni wọn ti yọ DPO yii nipo fun iwa aika-nnkan-si, bẹẹ ni wọn ni ko ko gbogbo iwe ati aṣẹ ipo rẹ fun ẹni to jẹ ọga to tẹle e, oju-ẹsẹ naa ni wọn si ti ni ko fara han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, niluu Abẹokuta.

Bakan naa la gbọ pe ijiya nla ti wa fun awọn agbofinro to gbe ọmọkunrin yii lọ sọsibitu to fi sa lọ mọ wọn lọwọ.

ALAROYE gbọ pe ara Lekan to jẹ dẹrẹba awọn oloogbe yii ko balẹ nigba to ti gbọ pe ọmọọdọ awọn mọlẹbi naa tawọn to pa wọn ju sodo pẹlu ọmọ wọn ko ku ni tiẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ọmọọdọ yii ati ọmọ awọn tọkọ-taya naa, Ọrẹoluwa ni wọn de lọwọ ati ẹsẹ, ti wọn si ju wọn sinu odo Ogun. Ṣugbọn ọmọọdọ yii jajabọ ni tiẹ, o ṣalaye fawọn agbofinro pe ninu ọkọ ayọkẹlẹ tawọn agbanipa naa gbe wa ni wọn ti de awọn lọwọ, ki wọn too ju awọn mejeeji sodo Ogun. O loun ja pitipiti titi, Ọlọrun si ba oun ṣe e ti ọwọ oun kan yọ jade ninu okun ọhun, loun ba luwẹẹ jade. Ọjọ kẹta iṣẹlẹ yii ni wọn ri oku ọmọ kan ṣoṣo to ku fun awọn tọkọ-tiyawo yii to lefoo sori odo Ogun. O loun loun ta awọn apẹja lolobo pe wọn ti ju eeyan kan sodo. Latigba naa lo ti wa lọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, nibi to ti n ran wọn lọwọ lori iwadii wọn nipa iṣẹlẹ aburu yii.

Ibi ijọsin adura alaja ọdun, eyi tọpọ awọn ẹlẹsin Kirisitẹni maa n lọọ gba lalẹ ọjọ to kẹyin ninu ọdun si idaji ọjọ ki-in-ni, ọdun tuntun, ni tọkọ-taya Kẹhinde Fatinoye ati Bukọla Fatinoye ti n dari bọ lafẹmọju ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ ki-in-ni, oṣu Ki-in-ni, ọdun 2023 yii. Ko pẹ ti wọn wọle to wa laduugbo GRA Ibara, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, tan lawọn afurasi agbanipa naa wọle tọ wọn, wọn pa wọn nipa ika, lẹyin naa ni wọn si dana sun oku wọn.

Banki apapọ ilẹ wa, Central Bank of Nigeria, ẹka ti Abẹokuta, ni baale ile yii ti n ṣiṣẹ, akọwe agba si ni iyawo rẹ ni fasiti ẹkọ nipa iṣẹ agbẹ, iyẹn Federal University of Agriculture, FUNAAB, l’Abẹokuta.

 

Leave a Reply