Elisha yii yoo pẹ ni Kirikiri o, ọmọkunrin ti ko ju ọdun mẹsan-an lọ lo fipa ba lo pọ

Adeoye Adewale

Ko sẹni to ti i le ṣalaye ohun ti awọn agbalagba ti wọn ti balaga, ti ọpọ awọn mi-in si niyawo nile, ti wọn ti bimọ tiwọn naa maa n ri lara awọn ọmọ keekeeke ti wọn maa n fipa ba lo pọ.  Eyi to asi buru ju nibẹ ni awọn to tun maa n lọwọ ninu ibalopọ akọ si akọ, iyẹn awọn ti wọn maa n ba ọkunrin ẹlẹgbẹ wọn lo pọ. Iru ẹ ni ti Opara Elisha, ẹni to lọọ ki ọmọ ọdun mẹsan-an to jẹ ọmọkunrin mọlẹ to si fipa ba a lo pọ karakara.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni adajọ ile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Ikeja, nipinlẹ Eko, sọ pe ki awọn ọlọpaa ṣi lọọ ju ọmọkunrin yii sọgba ẹwọn titi tigbẹẹjọ yoo fi tun waye lori ẹjọ rẹ lọjọ kẹta, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Ẹsun buruku ti wọn fi kan Elisha ni pe ṣe lo lọọ fipa ba ọmọdekunrin kan,  Dania Clearcut, ti ko ju ọdun mẹsan-an lọ sun ni agbegbe Meiran, nibi to n gbe.

Ohun ti ọrọ ọmọkunrin naa fi jẹ kayeefi ni pe ọkunrin ni ọmọ to ba lo pọ naa, oju furọ rẹ lo ki nnkan bọ, to si ba a lo pọ karakara. A gbọ pe Ojule kejila, Opopona Imam Abubarkar, niluu Meiran, ti Opara Elisha n gbe naa ni ọmọdekunrin ọhun n gbe.

Agbefọba, DSP K Ajayi, ṣalaye nile-ẹjọ pe iwa radarada ti Elisha hu pẹlu ọmọ naa ki i ṣe ohun to daa rara, ati pe ijiya nla lo wa fun ẹni to ba ṣe iru ẹ lawujo wa. O fi kun ọrọ rẹ pe ninu oṣu Keji, ọdun yii, ni afurasi ọdaran yii huwa naa, kọwọ too tẹ ẹ. Wọn ni ki i ṣe igba akọkọ ree ti Elisha yoo fipa ki ‘kinni’ rẹ bọ iho idi ọmọ naa.

Onidaajọ E. Kubenje, ko tiẹ gbọrọ kankan lẹnu ọdaran naa to fi sọ pe ki awọn ọlọpaa lọọ ju u sẹwon titi ti igbẹjo yoo tun fi waye lori ẹjọ rẹ, lọjọ kẹta, oṣu Karun-un, ọdun  yii.

Leave a Reply