Emefiele ma waa rogo o, ṣẹyin naa ti gbọ ohun ti wọn tun ṣe fun un ni kootu

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Afi bii alaisan ti wọn da duro lọsibitu, ti wọn ni ara rẹ ti ya, ko maa lọ sile, ṣugbọn ti ko tun pẹ ti wọn fi tun ru u pada lọ sọhun-un, to waa jẹ bo ṣe n kuro lọsibitu, bẹẹ lo n pada sibẹ. Bẹẹ gẹlẹ lọrọ ọga agba tẹlẹri fun banki apapọ ilẹ wa, Alagba Godwin Emefiele, to ti sun akata awọn agbofinro fun bii oṣu marun-un le diẹ, ti wọn si ti tun tatapo rẹ lọ si ọgba ẹwọn Kuje. Bo ṣe n kuro nile-ejọ lonii lo n pada sibẹ lọla.

Ni bayii, kootu ti tun ni ki wọn da a pada si ọgba ẹwọn Kuje ti wọn ti gbe e wa, pẹlu bi wọn ṣe ni ọkunrin naa kuna lori awọn ilana beeli ti ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Abuja, gbekalẹ fun un lori beeli ọọdunrun miliọnu ti wọn fun un.

Onidaajọ Hamza Muazu, ti ile-ẹjọ giga naa lo gbe idajọ kalẹ lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lasiko ti wọn foju afurasi naa han nile-ẹjọ ọhun pe ki wọn fun un ni beeli.

Muazu ni ki Emefiele lọọ wa oniduuro meji ti wọn gbọdọ ni dukia ilẹ lagbegbe Maitama, niluu Abuja, o gbọdọ ko iwe irinna rẹ fun akọwe kootu ile-ẹjọ, ko si gbọdọ kuro niluu Abuja. Bakan naa ni ko san ọọdunrun miliọnu Naira (300m), lẹyin eleyii, ko maa lọ sile layọ ati alaafia, ko si maa tile waa jẹjọ.

Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe Emefiele ko ri gbogbo awọn ohun ti wọn ni ko ko wa lati gba beeli rẹ, eyi to mu ki ile-ẹjọ paṣẹ ki wọn da a pada ṣọgba ẹwọn titi ti yoo fi ri gbogbo awọn ohun ti wọn ka siwaju ẹ, wọn si sun igbẹjọ si ọjọ kejidinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024.

Leave a Reply