Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Stephen John, lọwọ tẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, lori ẹsun fifipa b’awọn obinrin lo pọ niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọpọlọpọ awọn obinrin to wa lagbegbe Costain, niluu Ọrẹ, nitosi ibi ti ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Cross River naa fi ṣe ibugbe ni wọn ti lugbadi ibalopọ tipatipa lọdọ rẹ, ṣugbọn ti itiju ko jẹ ki wọn le sọrọ sita.
Inu oko ni wọn lo lọ maa n ka awọn iyawo oniyawo wọnyi mọ nigbakuugba to ba ti ṣakiyesi pe ẹni ọhun nikan lo wa nibẹ, lẹyin eyi ni yoo fa ada yọ si wọn lati fi dẹruba wọn, yoo si pa wọn lẹnu mọ titi yoo fi sohun to fẹẹ ṣe tan.
Nnkan bii aago meje aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karun-un, oṣu kẹjọ, ọdun ta a wa yii, ni wọn ni John tun ki ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹẹẹdogun kan, Fatimọ Yahaya, mọlẹ, to si fipa ba a lo pọ karakara.
Iṣẹ pajawiri kan ti iya rẹ, Abilekọ Oluwakẹmi Isaac, ran an lọjọ naa ni wọn lo fẹẹ lọọ jẹ ko too pade ọkunrin oni kinni ko-mọ-ọmọde ọhun lojugbo kan to gba kọja, nibẹ naa lo ti ki i mọlẹ, to si fipa ṣe kinni fọmọ ọlọmọ.
Nigba tọmọ dele to ṣalaye ohun toju rẹ ri fun iya rẹ, pẹlu ibinu lobinrin naa fi mori le teṣan ọlọpaa to wa niluu Ọrẹ lati fẹjọ rẹ sun.
Ni ibamu pẹlu alaye ti Ọgbẹni Bọlaji Salami to jẹ kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣe fawọn oniroyin, o ni ibi ti awọn ti n ọrọ wa ọdaran ọhun lẹnu wo lọwọ ni teṣan lawọn obinrin bii mẹta ti kọkọ yọju, ti wọn si n fidi rẹ mulẹ pe awọn naa wa lara awọn to waa yọ ada si nibi ti awọn ti n ṣiṣẹ ninu oko, to si fipa ba awọn lo pọ.
O ni afurasi ọhun ko ni i pẹẹ foju bale-ẹjọ niwọn igba to ti fẹnu ara rẹ jẹwọ pe loootọ loun ṣe awọn nnkan ti wọn fẹsun rẹ kan an.
Nigba ta a n fọrọ wa John lẹnu wo, ohun to n tẹnu mọ ni pe eedi lọrọ naa jọ loju oun, o ni ẹmi kan lo maa ba le oun leyii to ṣokunfa bi oun ṣe n siwa-hu.
Ọpọ igba lo ni oun yoo ti ṣe kinni ọhun tan koju oun too walẹ.