Ẹmi kan lo ni ki n maa gun awọn eeyan ni sisọọsi pa – Abdulafeez

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọkunrin kan, Abdulafeez Shorinmade, ẹni ọdun mẹtalelogun, ti sọ pe ti oun ba ti mu igbo yo tan ni ẹmi kan maa n sọrọ fun oun lati maa huwa buburu.

Lẹyin ti Afeez fi sisọọsi gun ọmọbinrin ẹni ogun ọdun kan, Rọfiyat Rasaki, lọrun niluu Iwo lọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ti iyẹn si gbabẹ dero ọrun aremabọ ni ọwọ tẹ ẹ.

Yatọ si ti Rọfiyat, ọmọ ọdun mẹtadinlogun yii tun lọ sagboole Soba, niluu naa, to si tun fi sisọọsi gun ọmọbinrin ẹni ọdun mejidinlogun miiran,  Sawiyu Nasrup.

Bo ṣe n ṣoro kaakiri yii lo mu ki awọn eeyan agbegbe naa tete lọọ fi ọrọ rẹ to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si tete lọ sibẹ lọọ mu Afeez to n gbe lagbegbe Feisu.

Lọdọ awọn ọlọpaa, Afeez ṣalaye pe lẹyin ti oun pari ileewe girama loun bẹrẹ si i mu igbo (indian hemp), o ni nigba ti ọrọ oun su awọn obi oun ni wọn ni ki oun lọ kọṣẹ keu ni ilu Iwo.

O ni latigba ti oun ti n fa igbo ni ẹmi kan ti maa n sọ nnkan ti oun yoo ṣe fun oun. O ni ki i ṣe pe awọn ọmọbinrin ti oun gun ni sisọọsi lalẹ ọjọ naa ṣẹ oun rara, ṣe ni ẹmi to n dari oun sọ pe ki oun maa gun wọn kaakiri.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe Sawiyu ti gba itọju nileewosan, o si ti lọ sile, ṣugbọn wọn ti gbe oku Sọfiyat lọ sile igbokuu-si fun ayẹwo.

Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe lẹyin iwadii ni Afeez ati ẹmi to n dari rẹ yoo lọ kawọ pọnyin rojọ ni kootu.

Leave a Reply