Faith Adebọla
Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, ti ṣọ pe oun ko ni i lọkan lati tẹ Buhari lẹsẹ mọlẹ o, ṣugbọn oun loun yoo ko sinu bata oṣelu to ba bọ silẹ, ti oun yoo si di aarẹ Naijiria lẹyin ti Buhari ba lọ tan lọdun to n bọ. Bẹẹ lo rọ awọn aṣofin pe ki wọn ṣatilẹyin fun ifẹ ọkan oun lati di aarẹ.
Yara kọkandinlọọọdunrun (301) to wa ni ileegbimọ awọn aṣofin agba lo ti ṣọrọ naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lasiko to ṣabẹwo sawọn asofin ọhun, to si beere fun atilẹyin wọn lori erongba rẹ lati di aarẹ Naijiria.
Tinubu ti Aarẹ awọn aṣofin naa, Ahmad Lawan, ṣaaju awọn ẹlẹgbẹ re lati ki i kaabọ ni, pẹlu bi oun ṣe ti jẹ gomina ipinlẹ, ti oun si tun ti dipo aṣofin mu, oun yẹ, bẹẹ loun kun oju oṣuwọn lati di aarẹ Naijiria.
Bakan naa lo gboṣuba fun awọn aladari aṣofin naa, o ni o ti fi iwa aṣiwaju ti ko lẹgbẹ han ninu isakoso rẹ gẹgẹ bii Aarẹ awọn aṣofin.
O fi kun un pe oun wa fun amọran, ifọwọsọwọpọ ati atilẹyin wọn. O ni awọn aṣofin yii le ṣe atilẹyin fun oun lati mu erongba oun ṣẹ.
Tinubu ni, ‘‘Mo ti sọ fun Aarẹ wa pe erongba mi lati di aarẹ ko fọ mi loju dẹbi ti ma a fi tẹ ẹsẹ Aarẹ mọlẹ, bata rẹ ni mo fẹẹ kẹsẹ bọ, ki i ṣe pe mo fẹẹ tẹ ẹ mọlẹ.’’
Nigba to n sọrọ lorukọ awọn aṣofin naa, Lawan ni oun mọ pe Tinubu kaju rẹ, o ni ipade to waa ṣe pẹlu awọn aṣofin yii kan wa lati foju rinju pẹlu wọn ni.
Lawan ni Tinubu ṣe daadaa gẹgẹ bii gomina, bẹẹ lo tun ti figba kan jẹ ọmọ ileegbimọ aṣofin agba.
Olori awọn aṣofin naa ni aadọrin lawọn tawọn jẹ aṣofin agba ninu ẹgbẹ APC, awọn si n reti awọn mẹta mi-in ti wọn ko ni i pe darapọ mọ awọn.