Monisọla Saka
Olori ilẹ wa nigba kan ri, General Yakubu Gowon, ti ni oun ni Ọlọrun lo lati yẹ ọjọ iku Aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, lọwọ ẹni to jẹ olori orilẹ-ede wa nigba naa, to si tun jẹ ologun, iyẹn Ọgagun Sani Abacha.
Gowon ni oun loun bẹ Abacha lati ma ṣe pa Ọbasanjọ, nitori bi wọn ṣe sọ pe o lọwọ ninu ete lati ditẹ gbajọba lọdun 1995.
Niluu Jos, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Plateau, lo ti sọrọ naa nibi ajọdun Keresi to da gbogbo ijọ Ọlọrun nipinlẹ naa pọ, eyi ti i ṣe akọkọ rẹ ti ijọba ipinlẹ naa ṣagbekalẹ.
Nigba ti Gowon jẹ alejo pataki nla, ti Ọbasanjọ naa si jẹ alejo pataki nibi eto naa. Gowon ni, “Mo kọ lẹta si Abacha, mo bẹ ẹ pe Ọlọrun lo fi i ṣe olori lati maa ṣe daadaa, ki i ṣe lati maa ṣe ibi.
“Iyawo mi ni mo fi lẹta naa ran laarin oru lati lọọ fun Abacha l’Abuja, mo bẹ ẹ pe iru nnkan bẹẹ yẹn ko gbọdọ ṣẹlẹ.
“Inu mi dun pe ko pẹ pupọ lẹyin igba naa, nnkan yipada, ki i si i tiẹ ṣe pe Ọbasanjọ fi ọgba ẹwọn silẹ nikan, o tun di aarẹ wa lọdun 1999.
“Nnkan to jẹ pe adura ati ootọ inu nikan le ṣe niyi. Inu mi dun pe lonii, emi ati Ọbasanjọ wa nibi lati ṣajọyọ iṣọkan ipinlẹ Plateau”.
Bakan naa ni Gowon dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ naa fun iru eto ti wọn gbe kalẹ ọhun, o ni yoo tubọ mu ki iṣọkan awọn eeyan ipinlẹ naa jinlẹ daadaa ni.
O ni aimọye wahala eto aabo to mẹhẹ ni wọn ti foju wi, nitori naa ni eto ayẹyẹ orin Keresimesi ti wọn pe ni Karoo ṣe jẹ nnkan pataki fawọn eeyan naa lati pe jọ yọ.
O tun gboṣuba kare fun Gomina Caleb Mutfwang, fun oniruuru eto to n gbe kalẹ lati ṣe igbelarugẹ fun ibagbepọ alaafia laarin awọn eeyan ipinlẹ naa.
Ka ranti pe lọdun 1995, ni Ọgagun Sani Abacha, fi panpẹ ọba gbe Ọbasanjọ, ti o si sọ ọ si atimọle pe oun naa wa lara awọn ti wọn n ṣeto lati ditẹ gbajọba lọwọ oun.
Pẹlu gbogbo ẹbẹ ti Ọbasanjọ bẹ lasiko naa, Abacha pada dajọ iku fun un ni.
Ọdun mẹta lo lo lọgba ẹwọn ko too ri itusilẹ gba lọdun 1998, lẹyin ti Abacha ku lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 1998 ọhun.