Adefunkẹ Adebiyi
Orilẹ-ede Naijiria nilo atunto gẹgẹ bi ọpọ eeyan ṣe n wi, koda, igbakeji aarẹ ile yii tẹlẹ, Atiku Abubakar, naa gba bẹẹ, oun si ti sọ pe bi atunto naa yoo ba waye, oun loun le jẹ ko wa si imuṣẹ.
Nibi ayẹyẹ ọjọọbi Oloye Raymond Dokpesi, Oludasilẹ ileeṣẹ DAAR Communications ni Atiku ti sọrọ yii. O fi kun alaye ẹ pe Naijiria nilo adari ti yoo mu iṣọkan wa, ti yoo ṣe atunto si gbogbo nnkan to n daru nilẹ yii, ti aabo ara ilu yoo si tun jẹ ẹ logun.
Ọkunrin ọmọ ipinlẹ Adamawa naa sọ pe atunto ti oun n sọ yii yoo ṣatunṣe si ọrọ aje Naijiria to ti bajẹ, o ni ṣugbọn ki i ṣe gbogbo awọn to n dije fun ipo aarẹ ni 2023 naa ni wọn lagbara lati ṣe atunṣe naa, bi ko ṣe oun Atiku Abubakar nikan.
Nibi ti ọrọ naa si da a loju de, gbangba lo ti da awọn akọroyin ti wọn beere lọwọ ẹ pe ṣe yoo si le ṣe eyi lo ti da wọn lohun pe ohun ti sọ bẹẹ tẹlẹ, ‘mo maa ṣe e”.
Pẹlu ipo aarẹ ti Atiku Abubakar fẹẹ du ni 2023 yii, eyi ni yoo jẹ igba kẹfa to ti n gbiyanju ipo naa. Atiku gbiyanju lati di aarẹ ni 1993, 2007, 2011, 2015 ati 2019.