Emi ni mo n gbọ gbogbo bukaata ninu ile, ọkọ mi tun n fẹsun agbere kan mi, ẹ tu wa ka- Rashidat

Adewale Adeoye

Iwaju Adajọ Hammed Ajumọbi, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan ti wọn n pe ni Area-Court, to wa ni Centre-Igboro, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ni awọn tọkọ-taya meji kan, Abilekọ Rashidat Bashir ati ọkọ rẹ, Ọgbẹni Ashọmu Bashir, gbe ara wọn lọ. Ẹsun ti Abilekọ Rashidat ti i ṣe olupẹjọ fi kan ọkọ rẹ ni pe ki i ṣetọju oun pẹlu awọn ọmọ toun bi fun un, ati pe ọpọ igba toun ba ti ṣọọbu de lo maa n fẹsun ṣina kan oun, leyii ti ko si ri bẹẹ rara.

O ni, ‘Oluwa mi, ọrọ mi ko pọ rara nile-ẹjọ yii, ohun ti mo n fẹ gan-an ni pe kile-ẹjọ yii tu igbeyawo to wa laarin emi pẹlu ọkọ mi ka, ki kaluku wa maa lọ ni ayọ ati alaafia, mi o ṣe mọ. Ko sifẹẹ kankan laarin awa mejeeji mọ.

Mi o le ranti igba ti ọkọ mi ti ṣojuṣe rẹ ninu ile lori awọn ọmọ rẹ tabi lori emi paapaa ti mo jẹ iyawo rẹ. Mo n fẹ ki wọn tu wa ka loju-ẹsẹ ni, nitori pe ọrọ ọhun ti fẹẹ ya mi ni were, mo ti ro o titi, mi o ri i ro mọ. Emi yii nikan ni mo n da gbọ gbogbo bukata inu ile pata, bawọn ọmọ wa ba nilo nnkan, emi ni mo n ṣe e fun wọn.

‘‘Ọkọ mi ko ri ọwọ kankan yọ rara. Mo maa n kiri ọja kaakiri ni ki ebi ma baa pa awọn ọmọ ti mo bi fun un, ṣugbọn eyi ti iba maa fi bẹ mi, ẹsun radarada lo fi maa n kan mi nigba gbogbo ti mo ba pada sile. Ṣe lọkọ mi aa maa sọ pe awọn ọkunrin ti mo n taja fun ti ba mi sun daadaa nita ni mo ṣe pẹ ki n too wọle, ojumọ kan, wahala kan ni, bẹẹ ebi maa pa awọn ọmọ wa ti mi o ba kiri ọja yii lojumọ kan’’.

Nigba to n dahun si ẹsun tiyawo rẹ fi kan an, Ọgbẹni Bashir ni ko soootọ kankan ninu ẹsun tiyawo oun fi kan oun yii, ṣugbọn ki wọn ba oun bẹ ẹ pe ko fọwọ wọnu lori ohun to n bi i ninu s’oun.

‘Ẹ ba mi bẹ ẹ pe ko ma binu si mi, mo ṣi nifẹẹ iyawo mi gidi. Mo fi da a loju pe laipẹ, gbogbo nnkan n bọ waa pada da fun wa ninu ile. Kẹ ẹ si ma wo o, nnkan bẹrẹ si i daru laarin emi pẹlu iyawo mi lẹyin ti iṣẹ ti mo n ṣe bọ lọwọ mi ni o, oun nikan lo n da gbọ gbogbo bukata ile loootọ, ṣugbọn irin ẹsẹ rẹ ko mọ to loju mi ni mo ṣe n ko o loju nigba gbogbo pe o n ṣe ṣina’’.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Hammed Ajumọbi, rọ olujẹjọ pe ko ṣọ ọrọ tabi ẹsun to fi maa n kan iyawo rẹ ninu ile, ko si ma fẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ kan an mọ. Bakan naa lo rọ iyawo to jẹ olupẹjọ pe ko yee rin irin alẹ tabi oru mọ rara, ko si mọ iru ọrẹ ti yoo maa ko lawujọ, ki wọn ma baa sọ ọ lẹnu.

O sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii.

Leave a Reply