Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, ti sọ pe oun ga ju awọn baba ati baba nla oun lọ.
Ninu ọrọ kan ti Ọba Akanbi fi sita lo ti ṣalaye pe oun ga ju Oduduwa, Ọbatọla, Ọrunmila, Ogun, Ṣango, Awolọwọ atawọn nla nla mi-in lọ
O ni ti oun ko ba ga ju awọn baba nla oun lọ gẹgẹ bii ọmọ wọn, o tumọ si pe ẹni ijakulẹ ni gbogbo awọn to wa lasiko yii ati ni iran to n bọ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ti mi o ba ti ju awọn baba mi lọ, a jẹ wi pe ẹyin awọn baba mi koda nu-un.Ẹyin baba yoo daa ni adura tí a ma ń gba tí àwọn bàbà wá bá papoda. Mo ga ju gbogbo awọn ti mo darukọ yii lọ, idi si niyẹn ti awọn ọmọ mi fi gbọdọ ga ju mi lọ.
“Eyi ni ala ati afojusun awọn baba ati baba nla wa”