Jọkẹ Amọri
Oludije sipo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu Labour, to tun jẹ gomina ipinlẹ Anambra nigba kan, Peter Obi, ti ṣọ pe arekereke ati eru wa ninu idibo aarẹ to waye ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii, ati pe awọn to wa nidii madaru naa ti pinnu lati fi esi idibo naa segbe lẹyin ẹni kan ni.
L’Ojọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta yii, lo sọ eleyii di mimọ niluu Abuja, lasiko to pe ipade oniroyin agbaye kan, nibi to ti ba awọn oniroyin sọrọ lori abajade esi idibo to waye ọhun.
Nigba to bẹrẹ ọrọ rẹ, Obi ni oun kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun to n bukun orileede wa, to si n daabo bo o. Ekeji ni idupẹ. Idupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn kopa ninu eto idibo yii, ti wọn gba ipe naa gẹgẹ bii ọmọ orileede rere. ‘‘Ẹkẹta idupẹ mi lọ sọdọ ẹyin ọmọ Naijiria, paapaa ju lọ, ẹyin ọdọ ti wọn gbagbọ, ti wọn si ṣiṣẹ takuntakun fun ireti Naijiria tuntun. Mo dupẹ lọwọ wọn fun iṣẹ takuntakun wọn, mo si dupẹ lọwọ ẹyin Obidient, ẹyin ọdọ ti ẹ gbagbọ pe Naijiria tuntun ṣee ṣe. Mo n fi asiko yii sọ fun wọn pe Naijiria tuntun ṣee ṣe, mo si maa ṣiṣẹ takuntakun fun eleyii.
‘‘Eto idibo ti a di kọja yii ti wa, o si ti lọ, wọn si ti ka esi idibo ti wọn ti ṣeto rẹ. O jẹ igbese titapa si ofin, ilana ati agbekalẹ ofin eto idibo. Eto idibo naa ko tẹwọn rara, ti a ba n sọrọ nipa eto idibo to lọ daadaa, ti ko si magomago, to si kun oju oṣuwọn. Yoo si wa ninu iwe itan pe o jẹ eto idibo to ni ariyanjiyan ti iru rẹ ko ti i ṣẹlẹ ri ni orileede wa.
‘‘Awọn aṣaaju wa ti a ro pe a nigbẹkẹle ninu wọn ti tun ja awọn eeyan daadaa, awọn ọmọ orileede yii to tẹpa mọṣẹ daadaa kulẹ. Mo wa n fi tọwọtọwọ bẹ gbogbo ẹyin ọmọ Naijira lati wa ni alaafia, ki ẹ tẹle, ki ẹ si huwa to ba ofin mu. Mo fẹẹ fi da yin loju pe emi ati Datti, ati ni pataki ju lọ, gbogbo wa, pe eyi ki i ṣe opin gbogbo rẹ, koda, a ṣeṣẹ bẹrẹ irinajo fun ibi Naijira tuntun ni. Datti Baba-Ahmed ati emi funra mi ko mikan rara, a gbagbọ ninu Naijiria tuntun ti a oo gbe kalẹ lori otitọ, akoyawọ, pin-in-re la-a-re.
Gbogbo ohun ti mo sọ yii duro lori igbesẹ. Ọna tabi Igbeṣe ti eeyan fi n depo ni ipilẹ to lagbara ju ohun ti tọhun n ṣe lẹyin rẹ lọ. Mo gbagbọ pe ẹnikẹni ti wọn yoo ba pe ni Ọlọla ju lọ ti yoo si dahun, ọna to tọ ati eyi to yẹ ni tọhun gbọdọ gab de ipo naa.
‘‘Mo fi n da ẹyin ọmọ Naijiria loju pe gbogbo ọna to ba ofin mu, to si tọna lati gba ẹtọ wa pada la maa lo.
Loootọ loootọ ni mo wi fun yin, awa la wọle eto idibo naa, ma a si ṣe afihan elelyii fun gbogbo ọmọ Naijiria.
‘‘Mo bẹ yin, ẹ ma jẹ ki ohunkohun da yin lagara, a ni eto idibo mi-in lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun yii, ẹ jade kẹ e lọọ dibo naa. Mo fẹ ko da yin loju pe gbogbo wahala ati ilakaka yin ki i ṣe lasan, awa naa ko si ni i kaaarẹ lati ṣagbekalẹ orileede ti inu awọn ọdọ yoo dun lati pe ni tiwọn…’’