Emi o le ki Gomina AbdulRazaq ku oriire o, o fowo ra ibo ni- Abdullah

 Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Oludije funpo gomina lẹgbẹ oselu PDP, to fidi-rẹmi nibi eto idibo ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, Alaaji Shuaib Yaman Abdullah, ti sọ pe laelae, oun ko le ki Gomina AbdulRazaq, iyẹn gomina to n ṣejọba lọwọ ni Kwara ti ajọ eleto idibo kede pe oun lo jawe olubori. O ni magomago pọ ninu eto idibo naa, ati pe o fowo ra awọn eniyan ni.

Lasiko ti Yaman n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, niluu Ilọrin, lo ti sọ pe oun ko ni i ki Gomina AbdulRazaq ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lẹẹkeji, ati pe oun ti fi ọrọ esi idibo naa le Ọlọrun lọwọ, oun yoo si pada sipinlẹ Kaduna, lati tẹsiwaju ninu ọrọ aje oun.

O fi kun un pe lẹyin gbogbo igbiyanju oun lati gbe ipinlẹ Kwara de ebute ogo, ki oun si gba ipinlẹ naa kalẹ lọwọ ijọba radarada, ṣugbọn ijọba to wa lode fowo ra awọn oludibo, eyi to mu ko pada sori aleefa.

Tẹ o ba gbagbe, Gomina Abdulrazak ni ajọ eleto idibo kede pe o jawe olubori ninu eto idibo ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun.

Leave a Reply