Titi dasiko yii ni bi ọkunrin yii ṣe ṣa iyawo ẹ atọmọ ẹ meji pa ṣi n ṣe awọn eeyan ni kayeefi, idi ni pe adura lo n gba lọwọ pẹlu iyawo naa atawọn ọmọ ọhun, afi bi ẹmi buruku ṣe gbe e wọ lojiji, lo ba ki aake mọlẹ, to si fi ṣa iyawo ẹ atọmọ wọn meji pa.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji, oṣu kọkanla yii, niṣẹlẹ aburu ọhun waye lagbegbe kan ti wọn n pe ni Woodlands, lorilẹ-ede Zimbabwe. Leo Kanyimo si ni wọn pe orukọ ọkunrin to dan mẹwaa wo yii.
Awọn araale wọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe afadurajagun ni Leo, ṣọọṣi Apostolic Faith Mission lo si n lọ, ko si ṣẹṣẹ maa gbadura fun ọpọlọpọ wakati ti awọn yoo maa n gbọ.
Lọjọ ti wahala ṣẹlẹ yii, wọn ni Leo sọ pe ẹmi ọkunkun n daamu ọkan lara awọn ọmọ oun, oun ati idile oun si ti bẹrẹ aawẹ ati adura tawọn yoo fi yọ ẹmi okunkun naa jade lara rẹ.
Adura ti wọn yoo fi le ẹmi okunkun ọhun jade lara ọmọ naa ni wọn n gba lọsan-an ọjọ Iṣẹgun yii pẹlu iyawo atawọn ọmọ wọn mẹta, nibi ti wọn ti n gba adura naa ni wọn ni Leo, ẹni ọgbọn ọdun, ti bẹrẹ si i ṣe bii ẹni ti Eṣu n ṣe, to n ṣe bii ẹlẹgun-un Ṣanpọnna. Nigba naa ni wọn lo mu aake to wa nitosi, lo ba fi ṣa iyawo ẹ, lo fi ṣa meji ninu awọn ọmọ wọn pa, ọmọ kẹta nikan lo raaye sa jade.
Nigba to pa wọn tan lo jade sita pẹlu oku ọkan lara awọn ọmọ to ṣa pa naa, nigba naa lawọn eeyan kegbajare sọlọpaa, ti wọn fi waa mu baba to pa idile rẹ run naa.
Ọlọpaa to n ri si iṣẹlẹ naa, Paul Nyathi, fidi ẹ mulẹ. O ni ọjọ ori iyawo Leo ko ti i to taati, ọgbọn ọdun. O ni ọmọ rẹ ọkunrin to jẹ ọmọ ọdun mẹwaa, ati obinrin to jẹ ẹni ọdun mejidinlogun lo ṣa pa.
O fi kun un pe awọn ti mu Leo ju satimọle, ẹmi to gbe e wọ ti kuro lara rẹ, o ku ko waa rojọ lori ohun to ṣe.