Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Bi awọn to n wọ ile ounjẹ Korona tijọba tọju ṣe n mọ ibẹ ko ye ọpọ eeyan to n lọ sibẹ lati ko ounjẹ ọhun, ṣugbọn ko jọ pe eyi wulẹ kan wọn tẹlẹ naa, bi wọn yoo ṣe maa mọ awọn ibi ti ile ounjẹ naa wa lo jẹ wọn logun, gẹgẹ bawọn eeyan kan nipinlẹ Ogun ṣe n wa ọna ti wọn yoo fi ri ile ounjẹ lọdọ tiwọn bayii, bi wọn ṣe ti ri i l’Ekoo, Ọṣun, Kwara atawọn ibomi-in.
Ohun ti pupọ ninu awọn ti akọroyin wa fọrọ wa lẹnu wo l’Abẹokuta, Mowe, Arigbajo, Ijẹbu-Ode, Arepo, Ilaro ati Ifọ sọ ni pe ko sohun to ni kawọn naa ma lọọ ja ile ounjẹ Korona gẹgẹ bii awọn ilu yooku. Wọn ni ai ti i mọ ibi ti iru ile ounjẹ bẹẹ wa nipinlẹ Ogun ni ko jẹ kawọn pẹlu ti ya bo ibẹ, kawọn si ko ounjẹ bamu bii tawọn ilu yooku kaakiri.
Koda, obinrin kan to pe orukọ ara ẹ ni Fumbi, ṣalaye pe Arepo loun n gbe, Erekuṣu Eko ( Lagos Island) loun si ti n ṣiṣẹ ni banki kan. O ni ṣugbọn pe oun n ṣiṣẹ ni banki ko tumọ si pe oun lowo lọwọ, iyẹn ko si ni ki wọn ri ile ounjẹ laduugbo oun koun ma lọọ gbe toun nibẹ.
Obinrin naa sọ pe ọmọ mẹta loun bi, oun ko lọkọ, nitori baba wọn ti fi oun silẹ lọọ fẹ iyawo mi-in lati bii ọdun mẹta sẹyin. Eyi lo ni o fa a to fi jẹ pe boun ba ri anfaani ounjẹ ọfẹ nibikibi nitosi Arepo yii, oun yoo lọ sibẹ lati ko toun.
Awọn ọdọ lo pọ ju ninu awọn ti wọn ni awọn n wa ile ounjẹ Korona yii, wọn ni yoo dun mawọn gidi bawọn ba le ṣawaari iru ile naa nipinlẹ Ogun.
Ẹ oo ranti pe lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii, lawọn eeyan ti n ko ounjẹ kẹtikẹti lawọn ibi ti wọn ti n ri wọn. Ilu Eko ni wọn ti kọkọ ri iru ile naa ni Mazamaza, ko too di pe wọn n ri i kaakiri awọn ilu bii Ekiti, Ondo, Ọṣun ati ni Jos to jẹ ilẹ Hausa.
Bo tilẹ jẹ pe iwa yii ku diẹ kaato loju awọn araalu mi-in, ti wọn si bu ẹnu atẹ lu u pe ko yẹ ki araalu lọọ maa fagidi ko ounjẹ tijọba ko fun wọn, sibẹ, awọn to ni awọn ko ran ijọba niṣẹ lo pọ, wọn ni nigba ti wọn ti ri awọn ile ounjẹ yii lawọn ilu yooku, ko si kinni kan to ni ki ipinlẹ Ogun naa ma ri tiwọn.