Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Arabinrin kan, Bola Owolabi, to jẹ olori awọn obinrin ninu ẹgbẹ PDP ni wọọdu kẹsan-an, nijọba ibilẹ Ado, ti wa ni ileewosan bayii. Eyi waye nitori ifarapa to ni ninu ija awọn ọmọ ẹgbẹ PDP to ṣẹlẹ niluu Ado-Ekiti l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Ija ajaku akata yii waye nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa n ṣepade ọlọsọọsẹ wọn laduugbo Odo-Ado, niluu Ado-Ekiti. Lasiko ija naa to gba bii ọgbọn iṣẹju ni Arabinrin Owolabi ti fara pa pẹlu bo ṣe foju gba igi ti ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ju, ti won si gbe e digba digba lọ sileewosan nibi to ti n gba itọju lọwọlọwọ.
Ọkan lara ọmọ ẹgbẹ PDP ti iṣẹlẹ naa ṣojú rẹ ṣo pe awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ti wọọdu kẹsan-an lo ko ara wọn jọ lati bẹrẹ ipade wọn,
ti olori awọn obinrin ni wọọdu naa, Arabinrin Bọla Owolabi, si dide lati sọrọ iṣaaju. Bayii ni awuyewuye kan sadeede waye, eyi to ja si ariyanjiyan laarin Arabinrin Owolabi yii ati Ọgbẹni Tosin Adebayọ, to jẹ amugbalẹgbẹẹ fun alaga ijọba ibile Ado-Ekiti tẹlẹ Ọnarebu, Ayọdeji Ogunṣakin.
Lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn ti bẹrẹ ija naa ni ẹjẹ bẹrẹ si i jade loju ati ni gbogbo ara Arabinrin Owolabi, eyi to jẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ yooku gbe e lọ si ileewosan lati gba itọju.
Lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa to ba ALAROYE sọrọ sọ pe Ọgbẹni Adebayọ, yii lo la igi nla kan mọ oju Arabinrin Owolabi nigba ti awuyewuye naa n lọ lọwọ.
Wọn sọ pe Ọgbẹni Adebayọ lo n ja fun Oloye Bisi Kọlawọle to fẹe ̣dije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti ninu eto idibo ọdun to n bọ ni ipinlẹ oun. Bisi Kọlawọle yii jẹ ọkan lara ọmọlẹyin Ayọ Fayoṣe to jẹ gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹri, ti gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ to jẹ ti Fayoṣe si n tẹle.
Nigba ti Arabinrin Owolabi n ja fun Igbakeji Gomina ipinlẹ ọhun tẹlẹ, Ọjọgbọn Oluṣọla Eleka, ti oun naa tun fẹe ̣dije fun ipo gomina, ṣugbọn ti ọga rẹ tẹlẹ yii ko fara mọ ọn.
Wọn ti fi ọrọ ija naa to awọn ọlọpaa to wa ni Okesa, niluu Ado-Ekiti, ati awọn ajọ obinrin agbẹjọro (FIDA) nipinlẹ Ekiti leti ki wọn le bẹrẹ igbesẹ ati iwadii lori ọrọ naa.
Gbogbo akitiyan ti ALAROYE sa lati ba olori awọn obinrin ninu ẹgbẹ PDP, naa sọrọ lo ja si pabo, pẹlu bo ṣe n gba itọju lọwọ nileewosan kan to jẹ ti aladaani niluu Ado-Ekiti ati pe oun ko fẹe ̣sọrọ lori ọrọ naa, ayafi ti awọn agba inu ẹgbẹ naa ba gbọ ọrọ naa.