Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Eeyan kan ku, nigba tawọn mẹta mi-in fara pa, ninu ijamba ọkọ to waye lopopona Wáríkò, si Lafiagi, nijọba ibilẹ Ẹ̀dù, nipinlẹ Kwara, lọjọ Iṣẹgun, Tosidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe oju-ẹsẹ ni awakọ ero naa to sare asapajude, Mohammed Idris, ku tawọn ero miiran, Usman, Bkatachi, ati Fati, toun jẹ obinrin si fara pa yanna-yanna.
Ọga agba ẹṣọ oju popo ni Kwara, Ọgbẹni Ogidan, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun, ni iṣẹlẹ agbọ bomi loju naa ṣẹ. Dẹrẹba to wakọ ero ọhun, Mohammed Idris, nikan ni wọn lo ku loju-ẹsẹ, nigba ti ero mẹta si fara pa yanna-yanna.
O ni loju-ẹsẹ ti wọn pe awọn lawọn ti de si ojuko ibi ti ijamba naa ti waye, ti awọn si sare ko awọn to ṣeṣe lọ sile-iwosan ijọba to wa ni Lafiagi. Mọsuari ọsibitu yii kan naa lo ni awọn gbe oku awakọ to ku si.
Caption kwara