Ẹni kan ku nibi ija ẹgbẹ APC ati PDP l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Agbọn n sẹ, ikamudu n sẹ, oju oloko ree gbankugbanku yii, bẹẹ lọrọ ri laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC nipinlẹ Ọṣun, latari bi awọn kan ṣe da ẹmi ọmọkunrin kan ti wọn n pe ni Ebenezer Alaro legbodo, niluu Ileṣa.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, niṣẹlẹ naa waye, iwaju ile baba rẹ to wa lagbegbe Aromirẹ, niluu Ileṣa, la gbọ pe wọn pa a si ni nnkan bii aago kan ọsan.

Ọkan lara awọn ọmọlẹyin Olori ileegbimọ aṣofin Ọṣun, Ọnarebu Timothy Owoeyẹ, ni Ebenezer, ipolongo ibo wọọdu si wọọdu la gbọ pe wọn lọọ ṣe laaarọ ọjọ iṣẹlẹ yii, to si jẹ pe oun lo wa mọto nla ti awọn oludije ẹgbẹ APC lagbegbe naa jokoo sinu ẹ.

Bi wọn ṣe pari ipolongo, gẹgẹ bi Akọwe iroyin Owoẹyẹ, Kunle Alabi, ṣe wi, lawọn ẹruuku naa tẹle e, ti wọn si pa a siwaju ile baba rẹ.

Latigba naa ni awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji ti n naka abuku siraa wọn. Adele alaga ẹgbẹ APC l’Ọṣun, Sooko Tajudeen Lawal, sọ pe lati ibẹrẹ ọsẹ yii lawọn tọọgi ẹgbẹ PDP ti n fa wahala kaakiri ilu Ileṣa.

O ni bi wọn ṣe n fa gbogbo patako ipolongo ibo ẹgbẹ APC ya ni wọn n yinbọn kaakiri ilu lati fi ko awọn araalu laya jẹ, ko too di pe wọn pa Ebenezer Alaro yii.

Lawal sọ siwaju pe ẹgbẹ APC jẹ ẹgbẹ ti ko gbagbọ ninu jagidijagan, idi niyẹn ti awọn ọmọ ẹgbẹ PDP fi n ro pe yiyọ ẹkun awọn, bii ti ojo ni.

Bakan naa ni Abẹnugan Owoẹyẹ ke si Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Longẹ, lati tete ṣawari awọn to pa Ebenezer, ki wọn si fimu kata ofin lati le jẹ ekọ fun awọn tọọgi oloṣelu to ku.

Amọ ṣa, adele alaga ẹgbẹ PDP l’Ọṣun, Dokita Adekunle Akindele, ti sọ pe ṣe ni ki ẹgbẹ APC lọọ tẹ ara wọn ninu, nitori awọn gan-an ni oniwahala.

O ni wọn ti da jinnijinni bo awọn eeyan ilu Ileṣa bayii pẹlu bi wọn ṣe n fi gbogbo igba yinbọn lakọlakọ, ti wọn si n fa gbogbo posita awọn oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ya kaakiri.

Ọwọngogo Naira:Awọn ọmọlooku lawọn ko gba owo atijọ, ni wọn ba gbe POS kalẹ fawọn eeyan

Leave a Reply