Ẹni kan ku, ọpọ fara pa, lasiko ija awọn Hausa ati Fulani l’Ọgbẹsẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ija ajakuakata kan to waye laarin awọn ọmọ Hausa ati Fulani to fi ilu Ọgbẹsẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, ṣebugbe ti ran ẹni kan sọrun apapandodo, ti ọpọ awọn eeyan si tun fara pa yannayanna.

ALAROYE gbọ pe, alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni wahala ọhun kọkọ bẹrẹ laarin awọn oniṣowo Hausa atawọn bororo kan, bi ilẹ ọjọ keji ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, ṣe n mọ ni wọn tun ko si ija wọn.

Ninu rogbodiyan ọhun ni wọn pa ẹni kan si, ti awọn miiran si ṣeṣe, wọn dana sun awọn ṣọọbu kan to jẹ tawọn Hausa, bẹẹ ni wọn tun ba ọpọ dukia olowo iyebíye jẹ.

Gbogbo ṣọọbu itaja ni wọn ti pa, ti ko si sẹni to laya lati waa na ọja nla to wa niluu Ọgbẹsẹ, laarin asiko ti ija naa fi waye.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Seriki awọn Hausa l’Ọgbẹsẹ, Ọgbẹni Aminu Abubakar, ni nnkan bii aago meji oru lawọn Fulani waa ya bo awọn Hausa.

O ni akọlu naa ba awọn lojiji, leyii to mu ki ọpọ wọnu igbo lọ lati sa asala fun ẹmi rẹ. Yatọ si tawọn ti wọn fara pa loriṣiiriṣii, o ni awọn Fulani ọhun tun dana sun ṣọọbu meje ati mọṣalaasi kan to jẹ ti awọn Hausa.

Ọkan ninu awọn agba ilu ọhun to tun ba wa sọrọ, Ọgbẹni Adekunle Augustine, ni ni kete ti rogbodiyan ọhun ti fẹẹ bẹrẹ lawọn ti sare pe awọn ẹṣọ alaabo, seriki awọn Hausa atawọn mi-in ti awọn tun ranti lati pe, ki wọn le waa pana rẹ, ṣugbọn awọn Fulani ṣi papa tẹsiwaju ninu akọlu wọn.

Akọwe ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, Ọgbẹni Olubiyi Emmanuel, ninu ọrọ tìrẹ dupẹ lọwọ awọn ẹṣọ alaabo ti wọn tete de lasiko ti rogbodiyan ọhun ko fi raaye gbilẹ ju bo ṣe yẹ lọ.

Awọn ọlọpaa ni wọn pada waa pana wahala ọhun lẹyin bii wakati diẹ ti wọn ti wa lẹnu rẹ, bẹẹ ni a ko ti i rẹni sọ fun wa ohun to fa ede aiyede laarin awọn ara Oke-Ọya naa.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, ni ọrọ ọhun ki i sọrọ ija ẹlẹyamẹya, bo tilẹ jẹ pe loootọ lawọn janduku kan lọ sinu ọja Ọgbẹsẹ loru, ti wọn si lọọ ba awọn ṣọọbu kan jẹ.

Leave a Reply