Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Lasiko ijaagboro to waye fun bii wakati kan aabọ gbako laarin ẹṣọ Amọtẹkun atawọn Hausa to wa lagbegbe Atikankan, l’Ado-Ekiti, ni eeyan kan ti gbẹmi-in mi, nigba ti ọpọ fara pa yanna-yanna. Ko din ni mẹrin lara awọn ẹṣọ Amọtekun to fara pa yanna-yanna nibi iṣẹlẹ ọhun.
Adugbo Atikankan yii ni awọn Hausa ati awọn ẹya mi-in maa n saaba gbe ni Ado-Ekiti, ti wọn si ti n ta ọja. O jẹ ibi ti awọn eeyan maa n bẹru gidigidi nitori wọn tun maa n ta igbo ati awọn egboogi oloro mi-in nibẹ.
Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe ni kutukutu aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un yii, lawọn ẹṣọ Amọtẹkun yii lọ si adugbo naa lati lọọ le awọn oniṣowo naa kuro ni ojuko naa. Ṣugbọn ọrọ naa kọja bi wọn ṣe ro pẹlu bi awọn Hausa wọnyi atawọn janduku miiran ṣe kọju ija si awọn ẹṣọ Amọtekun naa.
Lasiko naa ni ibọn ba ẹnikan ti wọn ko ti i mọ orukọ rẹ, ti wọn si gbee digba-digba lọ si ileewosan, nibi ti awọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe o ti jade laye.
Ko din ni mẹrin lara awọn ẹṣọ Amọtẹkun to fara pa yannayanna, bẹẹ ni wọn si ba ọkọ ti wọn gbe lọ sibẹ jẹ.
Nigba ti akọroyin ALAROYE de adugbo naa lẹyin wakati diẹ ti iṣẹlẹ ọhun waye, niṣe ni adugbo naa da paroparo, bakan naa ni awọn ọlọpaa kogberegbe duro si gbogbo adugbo naa.
Alukoro ọlọpa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe ko din ni mẹrin lara awọn to da wahala silẹ ni adugbo naa ti ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ.
O ṣalaye pe awọn mẹrin tọwọ tẹ naa yoo foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori iṣẹlẹ naa. Bẹẹ lo ni awọn agbofinro ti da alaafia pada si agbegbe ọhun.
Bakan naa ni ọga Amọtẹkun ipinlẹ Ekiti, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, sọ pe awọn ọmọ ogun oun ko mura ija lọ si adugbo naa, wọn kan lọọ parọwa si awọn oniṣowo naa lati bọwọ fun ofin ijọba ni.
O fi kun un pe mẹrin ninu awọn ọmọ oun lo wa nileewosan lọwọlọwọ, nibi ti wọn ti n gba itọju.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii nijọba ipinlẹ Ekiti paṣẹ pe ki awọn Hausa atawọn oniṣowo miiran to wa laduugbo ọhun kuro, ti wọn si ti pese pese ọja mi-in fun wọn lati maa ba ka-ra-ka-ta wọn lọ.