Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Agbẹjọro Dokita Ramon Adedoyin to ni otẹẹli Hilton, niluu Ileefẹ, nibi ti akẹkọọ Fasiti Ifẹ, Timothy Adegoke, ku si lọdun to kọja, ti sọ pe ki ẹnikẹni to ba ni kamẹra CVTV to ka iṣẹlẹ to ṣẹlẹ loru ọjọ naa silẹ mu un sita.
Abiọdun Williams, ẹni to sọ eleyii ninu atẹjade kan to fun awọn oniroyin, ṣalaye pe ki iru ẹni bẹẹ lọọ fun awọn agbofinro ni kamẹra naa dipo ahesọ ti wọn n sọ kaakiri.
Laipẹ yii ni ahesọ n lọ kaakiri pe wọn ti ri kamẹra CCTV to ka iṣẹlẹ ọjọ naa silẹ, ati pe Dokita Adedoyin, ọmọ rẹ, ati awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa wa nibi ti wọn ti pa Tinothy laago mejila oru.
Agbẹjọro Abiọdun sọ pe ahesọ lasan ni, ati pe awọn ọlọpaa ko ti i gbe abajade iwadii wọn lori iṣẹlẹ naa jade rara.
O ni ko si Dokita Adedoyin nileetura Hilton lọjọ iṣẹlẹ naa, ko si si bo ṣe le wa ninu kamẹra ti wọn n sọ kaakiri, koda, odidi oṣu kan ṣaaju iṣẹlẹ naa, ko si layiika rara.
O fi kun ọrọ rẹ pe ọrọ ihalẹ ori ikanni ayelujara lasan ni ahesọ naa, ibanilorukọjẹ si ni.
Nitori naa, Williams ni “A n reti lati ri kamẹra to ṣafihan bi onibaara wa ṣe wọnu yara Adegoke, a si rọ Oriyọmi Hamzat lati ṣafihan kamẹra naa gẹgẹ bo ṣe n pariwo ti ariwo rẹ ki i ba ṣe ọna lati sọ Adedoyin di ọta awọn araalu.”