Monisọla Saka
Ẹgbẹ awọn agbarijọpọ nọọsi atawọn agbẹbi nilẹ Naijiria, ẹka ti ipinlẹ Eko, National Association of Nigeria Nurses and Midwives, (NANNM), ti ni nọọsi to fun ọkunrin olorin to ṣalaisi laipẹ yii, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, ti wọn n pe ni Mohbad, labẹrẹ ko too di pe o ku, to si ti wa lakata awọn agbofinro bayii ki i ṣe ọkan lara awọn, nitori ki i ṣe ojulowo nọọsi to ni iwe-ẹri.
Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹsan-an, ni Akọwe ẹgbẹ naa, Tọba Odumoṣu, fi atẹjade naa sita.
O ni gbogbo ara lawọn fi fọwọ si iwadii lati mọ nnkan to ṣokunfa iku ọkunrin olorin naa, ati pe gbogbo ileeṣẹ tọrọ naa kan ni ki wọn jọọ ṣiṣẹ bii iṣẹ lati ri i pe wọn ri idajọ ododo gba lori iku ẹ.
“Awa ẹgbẹ nọọsi ati agbẹbi (NANNM), ẹka ti ipinlẹ Eko ranṣẹ ibanikẹdun si mọlẹbi, ara ati ọrẹ oloogbe Ilerioluwa Alọba, to ṣalaisi. Adura wa fun yin ni pe ki Oluwa duro ti yin.
A gbọdọ fidi pataki imọọṣe ati jijẹ ojulowo nidii iṣẹ ẹni han ninu iwadii ati ikede iwadii naa. Pẹlu gbogbo ara ni ẹgbẹ NANNM naa fi n ba iwadii ati ọrọ yii lọ. Iwadii ta a ṣe fihan pe ẹni ti wọn mu si atimọle ọlọpaa, ti wọn ni oun lo tọju Mohbad, ki i ṣe ojulowo ati akọṣẹmọṣẹ nọọsi to ni iwe-ẹri ninu ẹgbẹ yii.
“A n fẹ ki wọn wadii lori iru iwe-ẹri to wa lọwọ iru ẹni bẹẹ, ati ibi to kawe de, ki wọn too pe iru ẹni bẹẹ ni nọọsi tabi dokita alabẹrẹ.
Ko si aaye fun nọọsi ti ko kọṣẹ doju ami ti wọn n pe ni ‘auxiliary nurse’ ninu ẹgbẹ wa, tabi ninu eto ilera orilẹ-ede yii, ti iru ẹni bẹẹ ki i baa ti i ṣe akọṣẹmọṣẹ nọọsi to kawe gba iwe-ẹri, a jẹ pe ki i ṣe nọọsi niru ẹni bẹẹ, o kan n ṣiṣẹ to kọja òye ẹ ni.
“Bakan naa ni a tun n fi asiko yii ke si gbogbo awọn to n ṣewadii ọrọ yii atawọn oniroyin to n fi to araalu leti lati ṣe pẹlẹpẹlẹ, ki wọn si ṣootọ ninu iroyin iwadii ti wọn n gbe jade. Nitori a ko ni i gba ki wọn yi iṣẹ wa tabi nnkan ti iṣẹ nọọsi yii da le lori pada”.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe fidi ẹ mulẹ, wọn ni lilu ti wọn lu Mohbad nibi to ti lọọ ṣere lagbegbe Ikorodu lo ti fi gbogbo ara ṣeṣe, nọọsi ti wọn n sọrọ ẹ yii ni wọn ni wọn ke si lati waa tọju ẹ nigba ti ko yee pariwo ara riro.
Abẹrẹ to n pa kokoro to ba ba ibi oju egbo wọle sinu ara, to si le gbẹmi eeyan ti wọn n pe ni Abẹrẹ tetanus (Anti-Tetanus Injection), ni wọn sọ pe nọọsi naa loun fun Mohbad.
Ni kete ti wọn gun un labẹrẹ yii tan ni wọn sọ pe Mohbad bẹrẹ si i na wọn-ọn, nigba to di pe eemi ẹ n se, ti ko ribi mi daadaa mọ ni wọn sare gbe e lọ sile iwosan.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, ti wọn hu oku Mohbad, lati ṣayẹwo iru iku to pa a, ni awọn agbofinro fi panpẹ ofin gbe nọọsi ti wọn lo kọkọ tọju ẹ lati waa ṣalaye nnkan to mọ nipa iku ẹ ati iru abẹrẹ to gun un.