Ẹnikẹni to ba di aarẹ ti ko ba fi ti Peter Obi ṣe n tanra rẹ jẹ ni-Fayoṣe  

Jọkẹ Amọri

‘‘Ẹnikẹni ti wọn ba kede gẹgẹ bii aarẹ ilẹ Naijiria, amọran mi fun tọhun ni lati ri i pe o ṣiṣẹ papọ pẹlu Peter Obi ti i ṣe oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour, eleyii lo le mu anfaani nla wa fun orileede wa’’.

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹ̀ẹ, ayọdele Fayoṣe lo sọrọ naa lọ jọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji to ṣẹṣẹ pari yii, lasiko ti ileeṣẹ tẹlifiṣan TVC gba a lalejo.

Gomina ti oun naa n jẹ Peter yii sọ pe ẹni to gbọn ṣaṣa, ti ẹnikẹni ko si le fọwọ rọ sẹyin tabi foju di ni ọkunrin oloṣelu gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ ọhun.

O fi kun un pe Peter Obi jẹ ẹnikan ti ko nigbagbọ ninu a ko ọrọ jọ, ẹni ti nnkan kekere maa n to ni, o si ni ọkan otitọ ti ẹni to ba fẹẹ dari orileede yii nilo lati ṣe bẹẹ.

Fayọṣe ni Peer Obi ki i ṣe ẹni ti eeyan n foju kere, o ti di nnkan pataki ninu ọrọ oṣelu Naijiria bayii pẹlu ohun to ṣẹlẹ lasiko eto idibo ilẹ wa to ṣẹṣẹ pari yii. Gomina Ekiti tẹlẹ naa ni ẹnikẹni to ba wọle si ipo aarẹ ti ko ba fi ti Obi ṣe yoo ni wahala gidigidi, bẹẹ ni ijọba rẹ ko ni i tọjọ.

Nigba to n ṣapejuwe ọkunrin to ṣe ipo kẹta ninu ibo aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ kede rẹ yii, o ni ọkunrin yii ti di igi araba kan, o si gbọn ṣaṣa. O ni o gbagbọ ninu iwọntunwọnsi, funra rẹ ni yoo gbe baagi rẹ, o si maa n sọ fun awọn to ba leti lati gbọ pe bata ti oun ba wọ ki i ṣe ko jẹ olowo gegere, bi ko ṣe ki o rọrun foun lati wọ sẹsẹ, ko si gbe oun debi ti oun n lọ.

Fayọṣe ni bii ẹgun ni ọkunrin naa ri lara ọpọ awọn aṣaaju oloṣelu nilẹ wa, ati pe Obi ki i ṣe ẹni ti ẹnikẹni le dunkooko  tabi halẹ mọ.

Leave a Reply