Jọkẹ Amọri
Minisita fun ọrọ abẹle nilẹ wa, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti fofin lelẹ pe ẹnikẹni ti wọn ba kẹẹfin pe o n gbiyanju lati kọ lu ọgba ẹwọn eyikeyii nilẹ wa, niṣe ni ki wọn yinbọn pa irufẹ awọn eeyan bẹẹ.
O fi aṣẹ yii lelẹ fun aaọn lọgaalọgaa ọgba ẹwọn to wa ni Agodi, niluu Ibadan, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lasiko to lọọ ṣayẹwo si awọn ohun eelo ti wọn n lo nibẹ
Arẹgbẹṣọla ni niwọn igba to ti jẹ pe ibi to lewu ni ọgba ẹwọn fun awọn eeyan, ko yẹ ki ẹnikẹni to ba kọ lu iru agbegbe bẹẹ wa laye, ọrun lo yẹ ko ti lọọ maa rojọ ohun to wa lọ sibẹ.
Minisita yii kilọ pe ki awọn ọga ọgba ẹwọn naa ri i pe ẹnikẹni ko ṣe akọlu si ọgba ẹwọn mọ. O ni ohun ti oun fẹẹ maa gbọ ni pe wọn gbiyanju, ki i ṣe pe wọn wọ ibẹ. Bẹẹ ni aọn ọga ọgba ẹwọn yii si gbọdọ ṣiṣẹ takuntakun lati daabo bo ọgba ẹwọn naa.
O bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe n kọ lu ọgba ẹwọn, eyi to ni o gbọdọ dopin, ati pe igbesẹ to buru jọjọ ni ki wọn gbe lori ẹnikẹni to ba dan iru rẹ wo. Bẹẹ lo kilọ pe ki wọn ṣọra lati ma ṣe yinbọn lu alaiṣẹ.
Lasiko abẹwo yii ni Arẹgbẹṣọla paṣẹ pe ki wọn wo gbogbo ṣọọbu atawọn ile itaja mi-in to wa ni gbogbo agbegbe ti ọgba ẹwọn naa wa.
Bakan naa lo fi wọn lọkan balẹ pe ijọba yoo ri si eto igbaye-gbadun wọn, eyi ti yoo jẹ koriya fun wọn lati le ṣiṣẹ takuntakun si i.