Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu awọn afurasi mẹta kan, Dauda Wasiu, ẹni ọdun mẹtadinlogun, Qowiyu Kareem, ẹni ọdun mejidinlogun ati Daud Bello, ẹni ọdun mejidunlogun, ti wọn jẹ mẹkaniiki fẹsun pe wọn maa n ji ẹnjinni ọkọ atawọn eroja ara ọkọ mi-in gbe.
Agbẹnusọ ajọ naa, Babawale Zaid Afolabi, sọ pe Dada Durojaye ati Jamiu Fawaz, wa lara awọn igaara ọlọsa marun-un to jẹ pe ṣọọbu awọn mẹkaniiki ni wọn ti maa n lọọ ji ẹnjinni ati eroja ara ọkọ niluu Ilọrin, ti awọn si ti n dọdẹ awọn meji to ku bayii, ti ọwọ yoo si ba wọn laipẹ.
Afọlabi tẹsiwaju pe ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ni Arakunrin kan, Yusuf Muritala, mu ẹsun wa pe ẹnjinni ọkọ ti dawati ni ṣọọbu oun, to si darukọ awọn afurasi to ṣe e ṣe ki wọn ji ẹnjinni naa gbe. Wọn si pada mu awọn mẹta yii nibi ti wọn fara pamọ si ni agbegbe Ọffa Garage, niluu Ilọrin. Ọkan lara awọn afurasi naa, Dauda Wasiu, jẹwọ pe ẹgbẹrun meji naira pere loun pin nigba ti wọn ta ẹnjinni naa tan.