Monisọla Saka
Obinrin nọọsi alabẹrẹ kan to n ṣiṣẹ nileewosan tawọn dokita ti wọn n kanlẹ tọju oniruuru aisan wa, iyẹn Ahmed Sani Yariman Bakura Specialist Hospital, Gusau, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Zamfara, Asma’u Lawali Bungudu, ti ṣe bẹẹ gbẹmi-in mi, lẹyin to yọ ṣubu lẹnu iṣẹ.
Kokooko lara obinrin naa le nigba ti yoo wọṣẹ aarọ to wa, laaarọ kutukutu Ọjọruu Wẹsidee, ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹta ọdun yii, gẹgẹ bi iweeroyin Tribune ṣe ṣalaye, ṣugbọn niṣe ni wọn lo jade laye lẹyin wakati bii meloo kan to dẹnu iṣẹ.
Alukoro ile iwosan ọhun, Auwal Usman, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣalaye pe ẹnu iṣẹ ni Asma’u wa, ati pe o ti yẹ ipo ẹjẹ riru ati mimi soke ati sisalẹ awọn alaisan bii ọgbọn wo lọjọ naa ko too di pe o sọ fawọn dokita pe igbaaya n bu oun so.
Usman ni lẹyin to sọ bi ara ẹ n ṣe n ṣe e fun dokita tan lo ṣubu lulẹ, ni kiakia lawọn dokita ti sare ṣugbaa ẹ lati doola ẹmi ẹ, ṣugbọn gbogbo akitiyan awọn dokita naa ja si pabo pẹlu bi arẹwa obinrin naa ṣe ku loju-ẹsẹ.
O ṣalaye siwaju si i pe awọn igbimọ ileewosan ọhun, eyi ti adari eto iwosan l’ọsibitu naa, Dokita Usman Muhammad Shanawa, jẹ aṣaaju fun, ti gbe oku obinrin naa fawọn mọlẹbi ẹ.
Ọkan ninu awọn mọlẹbi oloogbe to sọrọ ṣalaye pe koko lara Asma’u le, ko si sohun to n ṣe e nigba to fi maa jade nile laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọhun, to fi mori le ọsibitu to ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bii nọọsi. Iyalẹnu lo jẹpe oku rẹ ni wọn pe awọn mọlẹbi lati waa gbe lẹyin wakati diẹ.
O ni wọn ti sinku ọmọbinrin naa nilana ẹsin Islam, ninu ile Malan Abdulrahaman, agbegbe Magama, Bungudu, nipinlẹ Zamfara, laago marun-un ọjọ Wẹsidee kan naa to jade laye.