Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ẹka tipinlẹ Kwara, ti tẹ awọn ajinigbe atawọn adigunjale mẹwaa nipinlẹ naa, ti ọkan lara awọn ajinigbe naa, Abubakar Ibrahim, si jẹ wọ pe awọn ko mọ pe adajọ ni Jumọkẹ Bamigboye ti awọn ji gbe ninu oko rẹ lagbegbe Ayegun, Ẹyẹnkọrin, niluu Ilọrin, lọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, tawọn si beere fun ọgọrun-un kan miliọnu Naira owo itusilẹ lọwọ mọlẹbi rẹ.
Abubakar Ibrahim, sọ fun iwe iroyin Saturday Sun, pe ipinlẹ Kano, loun dagba si toun ti n da maaluu koun too wa si ilẹ Yoruba fun isẹ ijinigbe ati idigunjale, tawọn si ti ji oniruuru eeyan gbe lọ sinu igbo. Awọn miiran n lo bii ọjọ marun-un lakata awọn, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa maa n di awọn lọwọ iṣẹ. O tẹsuwaju pe mẹẹẹdogun ni awọn ti wọn para pọ ti wọn jọ n ṣiṣẹ ijinigbe lẹnu bode ipinlẹ Kwara si Ọṣun.
O fi kun un pe ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, ni awọn ji adajọ naa gbe, tawọn si n beere fun ọgọrun-un kan miliọnu Naira lọwọ awọn mọlẹbi rẹ. Lẹyin eyi lawọn mọlẹbi dunaadura pe ọgbọn miliọnu Naira ni awọn lagbara lati san.
Ibrahim ni sadeede ni iro ibọn n dun lakọlakọ, eyi lo mu ki awọn fi obinrin adajọ naa silẹ, kawọn maa sa lọ, ṣugbọn asiko naa lọwọ ọlọpaa tẹ awọn, tawọn si jẹwọ fun wọn bi awọn ṣe n ṣiṣẹ ibi naa.
Ọkan ninu awọn ajinigbe ọhun to jẹ obinrin, Abibatu Jimoh, sọ pe ni bii ọdun kan sẹyin loun darapọ mọ ikọ ajinigbe yii, Iṣẹ toun maa n ba wọn ṣe ni ko fun awọn ti wọn ba ji gbe lounjẹ. O tẹsiwaju pe gaari ati awọn ounjẹ miiran loun maa n fun awọn ti wọn ba ji gbe to wa lakata awọn jẹ.
Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, Paul Odama, ni ọjọ keje, oṣu Kọkanla, ni ileeṣẹ ọlọpaa doola ẹmi adajọ ti wọn ji gbe, tọwọ si tẹ awọn afurasi mẹrin Abubakar Ibrahim, Mamud Ibrahim, Muhammed Kiri ati Abibatu Jimoh to jẹ obinrin. O ni gbogbo wọn ni yoo foju ba Ile-ẹjọ laipẹ.