Ẹrọ BIVAS yii lo maa ṣẹ awọn oloṣelu oniwayo lẹyin-Atiku

Faith Adebọla

Oludije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ninu eto idibo gbogbogboo to waye laipẹ yii, Alaaji Atiku Abubakar, ti sọ pe inu oun dun, ọkan oun si ti n balẹ wayii. O ni ẹrọ igbalode ti wọn fi n ṣayẹwo orukọ ati aworan awọn oludibo, iyẹn Bimodal Voter Accreditation System, BIVAS, lo maa ṣẹ awọn oloṣelu ti wọn ko mọ ju ṣiṣe eru ibo lọ lẹyin, poo.

Bakan naa lo ni ẹrọ yii ti ṣetẹwọgba nilẹ wa bayii, o si ti di apakan nnkan eelo idibo ti awọn adajọ paapaa n tọka si ninu awọn idajọ wọn lori ẹsun eto idibo bayii.

Atiku sọrọ yii lasiko to n fi idunnu rẹ han lori bi idajọ ile-ẹjọ giga ju lọ nilẹ wa ṣe da Gomina Ademọla Adeleke tipinlẹ Ọṣun lare lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un yii, ti wọn da ẹjọ ti gomina tẹlẹri nipinlẹ naa, Adegboya Oyetọla, pe ta ko idiboyan Adeleke nu bii omi iṣanwọ.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lati ọfiisi iroyin rẹ, Atiku ki Adeleke ku oriire idajọ to fidi ẹ kalẹ sori aga gomina ipinlẹ Ọṣun tepọn yii, bẹẹ lo ni ilo imọ ẹrọ ti tubọ mu ki Naijiria tẹsiwaju ninu eto idibo rẹ, a o si ni i rẹyin mọ.

O ni, “Gbogbo wa la ri i bi wọn ṣe n tọka si ẹrọ BIVAS leralera ninu idajọ tuntun yii. Ofin to de eto idibo ti fawọn eeyan lagbara daadaa wayi, ohun ti eyi si tumọ si ni pe awọn oloṣelu ti wọn n yan hanhan fun ipo ati agbara, bii igba ti ikoko n ba yan hanhan fun ọyan iya ẹ, ti wọn ro pe awọn le dori eto ijọba dẹmokiresi wa yii kodo bo ba ṣe wu wọn, ireti wọn ati ilakaka wọn ti ja sofo, ẹrọ BIVAS yii ti ṣẹ wọn lẹyin.”

Atiku waa gba gbogbo ọmọ Naijiria lamọran lati ma ṣe kaaarẹ ọkan, ki wọn ma si sọreti nu lori orileede yii, o ni ki wọn si fi ifẹ han si eto idagbasoke ijọba awa ara wa nilẹ yii, ki wọn rọ mọ ofin ati ilana, ki wọn si wa lojufo daadaa, tori oju lalakan fi n ṣọri, ẹni to ba si fẹẹ ja ija ominira ko gbọdọ toogbe rara, gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply