Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ẹsẹ ko gbero nile-ẹjọ giga to wa niluu Osogbo, nipinlẹ Ọṣun, nibi ti idajọ lori ẹjọ ti gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Adegboyega Isiaka Oyetọla, pe Gomina Ademọla Adeleke lori esi idibo ọdun to kọja, nibi ti gomina atijọ yii atawọn ọmo ẹgbẹ APC ti fẹsun kan Adeleke pe adiju ibo waye lawọn ibi kan nipinlẹ naa.
Fọfọọfọ ni awọn ọlọpaa, ọtẹlẹmuyẹ, awọn sifu difẹnsi atawọn ẹṣọ aabo loriṣiiriṣii kun ọgba kootu naa.
Lati ẹnu ọna abawọle ni awọn agbofinro ti n yẹ ara awọn to fẹẹ wọnu kootu naa wo lati ri i pe wọn ko wọnu ọgba kootu yii pẹlu awọn ohun to lodi sofin.
Bẹẹ ni awọn ọlọpaa wa kaakiri awọn agbegbe kọkọkan niluu Oṣogbo ti wọn mọ pe o ṣee ṣe ki wahala bẹ silẹ lẹyin idajọ naa.
Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ ninu ọgba kootu naa, ọkan ninu awọn agbẹjọro ẹgbẹ oṣelu PDP, Kọlapọ Alimi, fi idunnu rẹ han bi eto aabo ṣe wa ninu ọgba ile-ẹjọ naa. O gboriyin fun ọga agba ọlọpaa patapata nilẹ wa fun bo ṣe ko awọn eeyan rẹ jade, bẹẹ lo gboriyin fun kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun atawọn ẹṣọ alaabo yooku ti wọn wa nibẹ.
Alimi ni ireti awọn ni pe Gomina Ademọla Adeleke ni kootu yoo da lare, nitori oun lo bori idibo naa, ẹgbẹ APC kan n wa awawi nibi ti ko si lati kan gbe ẹjọ awuruju kalẹ ni.
Gbogbo bi idajọ naa ba ṣe lọ ni ALAROYE yoo maa fi to yin leti.