Esi ibo America daru mọ Donald Trump loju, o ni ‘bii idan lo ri loju oun
Pẹlu bi esi eto idibo to waye nilẹ America ṣe n jade diẹdiẹ yii, Aarẹ Donald Trump ti sọ pe niṣe lawọn esi ọhun n da bii idan loju oun, nitori gbogbo ibi toun ro pe oun ti wọle tẹlẹ lọrọ ti n di bami-in bayii.
O ni laṣaalẹ ọjọ Iṣegun, Tusidee, iroyin ti oun n gbọ ni pe oun loun n jawe olubori, paapaa lawọn agbegbe to jẹ pe ti ẹgbẹ oṣelu oun ni wọn n ṣe nibẹ, ṣugbọn bi nnkan ṣe n lọ bayii, o jọ pe niṣe lawọn ibo to yẹ ko gbe oun wọle kan bẹrẹ si ni poora ni.
Ṣaaju asiko yii ni Aarẹ Trump, ẹni to tun jẹ oniṣowo nla, ti sọ pe oun yoo gba ile-ẹjọ giga lọ lori esi ibo to n jade yii, nitori oun mọ pe ojooro lawon Joe Biden fẹẹ ṣe foun, oun gan-an lawọn eeyan America ṣi fẹ nipo aarẹ orilẹ-ede ọhun.