Ẹsun gbigbe oogun oloro: Afi ki Tinubu jade ko waa wẹ ara ẹ mọ– Peter Obi

Faith Adebọla

 Oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Ọgbẹni Peter Obi, ti gba ẹlẹgbẹ rẹ lati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, nimọran pe ko bọ sita lati fẹnu ara ẹ sọ bọrọ ṣe jẹ gan-an lori ẹsun to n ja ranyin nigboro pe ọkunrin naa ti lọwọ ninu ṣiṣe okoowo egboogi oloro ri, ati pe ile-ẹjọ kan l’Amẹrika ti da a lẹbi, ti wọn si gbowo gọbọi lọwọ ẹ lọdun 1993.

Obi sọrọ yii nipasẹ atẹjade kan lati ọfiisi eto iroyin fun ipolongo ibo rẹ, Obi-Datti Media office, eyi to fi lede lọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla yii.

Ninu atẹjade naa, Obi rọ Tinubu lati ma ṣe mu awọn ọmọ Naijiria lọbọ lori ẹsun yii, o ni ko tọna lati jẹ kawọn araalu maa mefo lori iru ẹni ti Tinubu jẹ gan-an ati ohun to ti ṣẹlẹ si i sẹyin, o ni ko lo anfaani yii lati ṣiṣọ loju eegun gbogbo ọrọ ti wọn n dawọ bo.

Atẹjade naa ka lapa kan bayii:

“Ohun to tubọ kọ wa lominu gidi ni bi oludije funpo aarẹ APC ko ṣe fẹnu ara ẹ sọrọ, bẹẹ ni ko fẹ kawọn ọmọ Naijiria bi oun leere ọrọ nipa atẹyinwa rẹ, to jẹ niṣe lo n dọgbọn yẹ gbogbo apero ita gbangba ati ipade pẹlu awọn oniroyin silẹ, ati bo ṣe n lo awọn agbẹnusọ atawọn to n ṣe bii aja ẹhanna lẹyin rẹ, lati maa fesi ọrọ fawọn ọmọ Naijiria, ki wọn si maa daṣọ aṣiri bo ẹgbin to ti ṣe sẹyin.

“Kaka ki wọn dówọ boju pẹlu itiju, niṣe ni wọn ko ẹwu igberaga kọrun ni ọfiisi ipolongo ibo fun Tinubu, ti wọn n dawọ bo irọ lori, tori eyi ni wọn ṣe n yan ode ita gbangba ti wọn ba fẹẹ lọ ateyi ti wọn maa yẹ silẹ.

“A gbọ pe ẹ ti gbe iwe eto bẹ ẹ ṣe maa ṣejọba ti wọn n pe ni manifesto jade, ṣugbọn ẹni to pese iru iwe bẹẹ gbọdọ wa laróọwọto lati ṣalaye lẹkun-unrẹrẹ ati lati dahun awọn ibeere taraalu fẹẹ mọ nipa bẹ ẹ ṣe maa ṣaṣeyọri awọn eto ati ilana iṣejọba tẹ ẹ to kalẹ ọhun.

“Bo ba jẹ loootọ ni Tinubu ti lọwọ ninu okoowo egboogi oloro ati kikowo rẹpẹtẹ wọlu lorukọ ẹlomi-in nigbakuugba ri laye ẹ, o ni lati ṣalaye ara ẹ fawọn ọmọ Naijiria ni.

“Bo ba si kọ, to bo aṣiri ara é mọlẹ, to tun fara pamọ fun ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, a gbọdọ gbe igbesẹ to tọna, kawọn ajọ ati ileeṣẹ ijọba tọrọ kan dide lati gba orileede yii lọwọ eeyan ti atilẹwa ẹ mu ifura lọwọ bẹẹ, iru ẹni bẹẹ o tiẹ gbọdọ gbooorun ipo aarẹ, ipo to ga ju lọ nilẹ wa.”

Obi tun ke si ajọ INEC lati kọwe si Tinubu pe ko waa wẹ ara ẹ mọ, tori iwe ofin eto idibo tọdun 2022 fun wọn lagbara lati beere ohun to ba ruju nipa oludije eyikeyii, o lohun tawọn ọmọ Naijiria n reti niyẹn.

Bakan naa ni Ọgbẹni Paul Ibe, ti i ṣe Oluranlọwọ pataki fun oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar, ti sọrọ lori iṣẹlẹ yii.

Ninu ọrọ kan to gbe soju opo tuita rẹ l’Ọjọbọ, Wẹsidee,  ọsẹ yii, o ni: “Ki i ṣe iroyin mọ bayii o pe lọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa, ọdun 1993, ijọba Amẹrika gbẹsẹ le ẹgbẹrun lọna ọtalenirinwo dọla ($460,000) owo Bọla Ahmed Tinubu tori okoowo egboogi oloro, ati daruke owo to ṣe, eyi to ta ko ofin ilẹ Amẹrika. Iwe ẹsun alabala mọkandinlọgọta yii ti fidi ẹ mulẹ.”

Ṣugbọn Tinubu naa ti fesi o. Bo tilẹ jẹ pe esi naa ko jọra, tori ọtọọtọ lawọn to sọrọ lorukọ gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri naa.  Ọgbẹni Bayọ Ọnanuga, ti i ṣe Alakooso eto iroyin ati ipolongo ibo fun Tinubu lo kọkọ sọrọ laaarọ Ọjọbọ, Wẹsidee, o ni awọn meji kan ti Tinubu ko mọ pe wọn n ṣe okoowo egboogi oloro ni wọn n ya akaunti ileeṣẹ Tinubu kan to wa lawọn banki meji tọrọ kan l’Amẹrika lo, awọn ni wọn n sanwo rọgunrọgun wọle sinu awọn asunwọn ọhun, ki awọn ọtẹlẹmuyẹ Amerika, awọn FBI, too tọpinpin ọrọ kan Tinubu, tile-ẹjọ si gbẹsẹ le awọn akaunti naa.

Ọnanuga ni ibi ti wọn yanju ọrọ naa si nigbẹyin ni pe ijọba Amẹrika gbẹsẹ le apa kan owo naa, o leyii lawọn alatako Tinubu sọ di babara, ti wọn n sọ pe ọga oun ṣokoowo egboogi oloro.

Amọ alaye mi-in ni olori agbọrọsọ fun igbimọ olupolongo ibo fun Tinubu ati Shetima, Amofin Agba Festus Keyamo, ṣe ni tiẹ.

Nigba to n dahun ibeere lori eto ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels laṣaalẹ ọjọ Wẹsidee yii kan naa, o ni ijọba orileede Amẹrika ni wọn tọpinpin awọn akaunti mẹwaa kan lati ibẹrẹ ọdun 1990, awọn akaunti mẹwaa naa si jẹ ti Bọla Tinubu.

O ni ki i ṣe Tinubu funra ẹ gan-an lo ni gbogbo awọn akaunti yẹn o, ṣugbọn nitori awọn mọlẹbi ẹ, bii mama rẹ, atawọn eeyan rẹ ti orukọ baba wọn papọ, eyi ni Tinubu fi gba pe oun loun ni wọn.

O ni bi wọn ṣe ri owo to wa ninu awọn akaunti naa, niṣe ni wọn kan fa ẹgbẹrun lọna ọtalenirinwo dọla ($460,000) yọ loju-ẹsẹ ninu ọkan lara awọn akaunti naa, wọn fi i ṣe owo-ori to yẹ ki Tinubu san lori okoowo to n fi awọn akaunti naa ṣe.

O tun ni ile ti Tinubu n gbe nigba naa lọhun-un l’Amẹrika, o lawọn kan ti wọn ṣe okoowo egboogi oloro lo n gbebẹ, Tinubu ko si mọ, adirẹsi ile yii lo si fi ṣi awọn akaunti naa ni banki. Ọrọ naa ko si ju bẹẹ lọ.

Lopin ọrọ rẹ, Keyamọ ni awọn alatako Tinubu, ni pataki, ẹgbẹ oṣelu PDP ati oludije wọn, ti wọn ko fẹẹ rimi rẹ laatan latari bo ṣe n dije fun ipo aarẹ, awọn ni wọn wa nidii gbogbo ọrọ yii. O fẹsun kan Atiku, bo tilẹ jẹ pe ko darukọ rẹ, pe laipẹ yii to loun lọọ ṣepade pẹlu awọn olokoowo kan l’Amẹrika, ipade ọtẹ Tinubu lo lọọ ṣe, abajade rẹ si lọrọ to n ja ranyin yii, tori ajẹ ke lanaa, ọmọ ku loni-in, ko sẹni ti ko mọ pe ajẹ to ke lanaa lo pa ọmọ to ku jẹ.

Keyamọ ni, ṣugbọn pẹlu ẹ naa, iti ọgẹdẹ lọrọ yii, ko to ohun aa lọ ada bẹ. O ladaba Tinubu o naani a n kungbẹ, ina n jo, ẹyẹ n lọ ni o.

Leave a Reply