Ọlawale Ajao, Ibadan
Pẹlu bi eto idibo ijọba ibilẹ ṣe n lọ lọwọ jake-jado ipinlẹ Ogun, Gomina ipinlẹ ọhun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti gba awọn ara ipinlẹ naa niyanju lati lọọ dibo fun ẹgbẹ oṣelu to ba wu wọn lai bẹru tabi fa wahala kankan.
Ni nnkan bii aago mọkanla aabọ ni Gomina Abiọdun dibo nibudo idibo keji, Wọọdu kẹta, lagboole Ìta Ọ̀sányìn, lagbegbe Ìrẹ́gùn, niluu Ìpẹru-Rẹmọ.
Yatọ si kansilọ ti wọn yinbọn pa lalẹ ọjọ idibo ku ọla, ALAROYE ko ti i gbọ pe wahala kankan ṣẹlẹ lọjọ idibo nibikibi kaakiri ipinlẹ naa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.
Amọ ṣa, aago mẹjọ aarọ lajọ eleto idibo ipinlẹ Ogun, Ogun State Indepent Electoral Commission (OGSIEC), sọ pe idibo yoo bẹrẹ, ṣugbọn eto ọhun ko bẹrẹ titi aago mẹwaa lọpọlọpọ ibudo idibo kaakiri.
Ninu awọn ilu bii Ìkẹ́nnẹ́, Ìliṣàn-Rẹ́mọ, Ṣàgámù, ati Ìpẹru Rẹmọ, ti akọroyin wa de, ko sibi ti wọn ti tete bẹrẹ idibo titi aago mẹwaa aarọ. Eyi ko ṣẹyin bi awọn oṣiṣẹ eleto idibo ko ṣe tete gbe awọn ohun eelo idibo de awọn agbegbe naa. Bo si ṣe ri ree lọpọlọpọ ibudo idibo niluu Abẹokuta, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa gẹgẹ bii iwadii akọroyin wa.
Nigba ti awọn oludibo duro titi di aago mẹsan-an aabọ, ti wọn ko ri awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo niluu Ṣagamu, nigba naa ni ijakulẹ ba awọn eeyan naa, ti wọn si bẹrẹ si i kanra mọ awọn oniroyin to lọ sibẹ lati ṣiṣẹ iroyin jẹẹjẹ wọn. Diẹ ninu awọn eeyan yii si ti n sọ ọ laarin ara wọn pe awọn yoo lu awọn oniroyin ko too di pe awọn onitọhun kuro nibẹ, ti wọn si tẹsiwaju ninu irinajo wọn.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni kete to dibo tan, Gomina Abiọdun fi idunnu ẹ han si bi eto idibo ọhun ṣe n lọ nirọwọrọsẹ lai si wahala kankan.
O gboriyin aṣeyọri ọhun fun olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, labẹ akoso CP Abiọdun Alamutu atawọn ileeṣẹ agbofinro yooku bii ajọ eleto aabo ilu ta a mọ si Sifu Difẹnsi, awọn Amọtẹkun ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “ẹ jẹ ki n kọkọ kan saara si ajọ OGSIEC (ajọ eleto idibo ipinlẹ Ogun) fun bi wọn ṣe gbaradi daadaa fun eto idibo yii to.
“Gẹgẹ bi awọn eeyan to tọpinpin eto gbogbo nipa idibo yii ṣe jábọ̀ fun mi, awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo yii n ṣiṣẹ wọn daadaa pẹlu ootọ inu.
“Loootọ, ko si eto idibo to maa waye ti ko ni i ni awọn kùdìẹkudiẹ kọọkan bii ki awọn ohun eelo idibo ma tete de si awọn ibudo idibo kọọkan, ṣugbọn ta a ba da a silẹ ta a tun un ṣa, wọn fi ye mi pe ajọ OGSIEC ṣe daadaa.
“Lẹyin naa, mo ni lati mọ riri awọn oṣiṣẹ eleto aabo, mo ti ri ogunlọgọ awọn ọlọpaa, Sifu Difẹnsi, Amọtẹkun, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Akitiyan wọn lo fi awọn eeyan lọkan balẹ ti wọn fi jade dibo pẹlu ifọkanbalẹ laisi ifoya.”
Nigba to n kan saara si awọn oniroyin fun bi wọn ṣe ta awọn ara ipinlẹ Ogun jí fun iroyin ti wọn n kọ nipa eto idibo yii nigba gbogbo, Gomina Abiọdun rọ gbogbo ara ipinlẹ naa lati gba alaafia laaye delẹ titi ti eto idibo ọhun yoo fi pari.