Nibi ipade ijiroro kan to ṣe pẹlu awọn adari ẹgbẹ oṣelu lo ti sọrọ naa niluu Abuja. O ni ohun to lo fa eleyii ni pe ko si awọn eeyan to forukọ silẹ ni awọn ibudo idibo yii.
Lara awọn ipinlẹ ti eto idibo naa ko ti ni i waye lawọn ibudo idibo kan ni ipinlẹ Zamfara, Kwara, Edo, Rivers ati ipinlẹ Imo, nibi ti eto idibo ko ti ni i waye lawọn ibudo idibo bii mejidinlogoji.
Yakubu ni pẹlu bawọn ṣe yọ ibudo idibo bii ọjilerugba yii, eto idibo yoo waye lawọn ibudo idibo bii mẹrindinlaaadọsan-an o le ẹgbẹta ati mẹfa (176, 606) kaakiri awọn ipinlẹ nilẹ wa.
O fi kun un pe ajọ naa yoo koro oju si ki awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu meji tabi ju bẹẹ lọ kora wọn jọ si ibudo idibo, ti wọn yoo si maa da wahala ati idarudapọ silẹ nibẹ. O ni wọn yoo mu ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n hu iru iwa bẹẹ, wọn yoo si fi i jofin.