Adeoye Adewale
Awọn iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ laye ode oni buru jai, to maa n ṣoro lati gbagbọ, bi ki i baa ṣe pe ọwọ tẹ ẹni to ṣe e tabi aworan rẹ ba wa nita faye lati ri.
Abi ki leeyan fẹẹ sọ si ti ọmọkunrin kan, Fraiday Samson, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29), to jẹ ọga akọrin ni ṣọọṣi, to fipa ba ọmọbinrin to kọnu ifẹ si tiyẹn ko gba fun un, Ruth Yakadi Bako, lo pọ, lẹyin to si ba a lo pọ tan lo tun pa a danu niluu Jos, nipinlẹ Plateau.
Nigba to pa a tan lo wọ oku arẹwa obinrin naa ṣegbẹẹ titi, iwadii ati iṣẹ itọpinpin awọn ọlọpaa lo si jẹ ki wọn ri ọmọkunrin to n ṣisẹ ọdẹ, to si tun jẹ ọga akọrin ni ṣọọṣi kan ọhun mu.
Nigba to n ṣalaye bọwọ ṣe tẹ afurasi ọdaran naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun, DSP Alfred Alabo, ṣalaye pe lọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2022, ni Ọgbẹni Fraiday Samson hu iwa ọdaju naa.
O ni latigba tawọn ti ri oku Ruth lẹgbẹẹ ibi ti wọn pa a si lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori rẹ. Ṣugbọn laipẹ yii lọwọ too tẹ ẹ leyin ti awọn agbofinro mu onibaara rẹ kan to ta foonu oloogbe naa fun, tiyẹn si jẹwọ pe Friday lo ta a foun.
Alukoro ni nigba tawọn n tọpinpin ọwọ ẹni ti foonu oloogbe wa ni awọn wa a de agbegbe kan bayii ti wọn n pe ni Angwan Jarawa, lẹyin-o-rẹyin lawọn si ri i pe ọwọ ọmọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Ephraim Emmanuel ni foonu ọmọbinrin naa wa.
Nigba ti wọn fọwọ ofin mu un lo ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, o ni ẹnikan lo ta foonu naa foun, bẹẹ lo si ṣeleri pe oun maa mu awọn agbofinro de ọdọ ẹni toun ti ra foonu ọhun. Bayii ni Emmanue mu awọn agbofinro lọ sọdọ Fraiday, ti wọn si fọwọ ofin mu un.
Nigba to n sọ lori ipa buruku to ko ninu bi Omidan Ruth Bako ṣe ku, Fraiday sọ pe oun paapaa gba pe ohun aburu gbaa loun ṣe, ati pe ṣe loun gba pe eṣu lo ya oun lo nipa bi oun ṣe gbero lati pa ọmọbinrin naa.
Afurasi ọdaran naa sọ ninu alaye rẹ pe ọkan lara awọn ọga akọrin ninu ijọ Ọlọrun kan ni agbegbe ibi toun n gbe loun, oun si tun n ṣiṣẹ ọdẹ nileepo kan. O ni lọjọ iṣẹlẹ yii, Ruth n bọ lati ibi iṣẹ ni, oun si da a duro lalẹ ọjọ naa, nitori gbara toun ti ri ọmọbinrin naa ni ẹwa rẹ ti wọ oun loju gidi gan-an, toun ko si le mu un mọra mọ rara. O ni ṣe loun sọ fun un lẹsẹkẹsẹ pe ko gba oun laaye lati ba a lo pọ lalẹ ọjọ naa, ṣugbọn oloogbe naa kọ jalẹ, o ni ko sohun to jọ ọ rara.
Fraiday ni pẹlu itara loun fi tẹle e de ibi kan to ṣokunkun daadaa, toun pẹlu rẹ si jọ ọ wọya ija lọjọ naa nitori ko fẹẹ gba foun, ṣugbọn nigba to jẹ pe agbara oun ju ti ẹ lọ loun ṣe lanfaani lati fipa ba a sun lọjọ naa. O ni ọmọbinrin yii tiẹ bẹ oun pe ki oun dawọ duro lọjọ naa, ṣugbọn oun ko gba, afigba toun tẹ ifẹ inu ara oun loun too dide lori rẹ.
Nigba to n ṣalaye idi to fi gbẹmi rẹ, ọmọkunrin to ni ọga akọrin loun ninu ijọ kan ti ko darukọ ọhun sọ pe ẹru pe ko ma baa waa fi ọlọpaa mu oun loun loun fi gbẹmi rẹ lalẹ ọjọ naa, toun si ji foonu ọwọ lọ.
Ọmọkunrin ọdaran yii ni o to oṣu kan daadaa lẹyin toun pa Oloogbe Ruth Yakadi Bako ko too di pe oun ṣẹṣẹ lọọ ta foonu rẹ fun ẹni ti wọn ka a mọ lọwọ bayii. O fi kun un pe ọmọ meji loun ti bi, oun ko si mọ ohun to ṣe oun toun fi ṣiwa-hu lọjọ naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti ni gbara tawọn ba ti pari gbogbo iwadii awọn nipa ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan Friday lawọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ fun idajo to peye lori ohun to ṣe.