Ẹwọn n run nimu Ṣẹgun atawọn ọrẹ ẹ, ẹru to lodi sofin ni wọn ba lọwọ wọn l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti wọ awọn ọrẹ mẹta kan wa sile-ẹjọ Majisreeti ipinlẹ Ekiti, pẹlu ẹsun pe wọn ka apo igbo nla kan to to bii aadọta kilo mọ wọn lọwọ.

Awọn mẹta naa ni: Ogundipe Ṣẹgun, ẹni ọdun mọkanlelogun, Ajayi Oluwaṣeun, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ati Blessing Ọmọtayọ, ẹni ọdun mẹẹẹdọgun. Ẹsun kan ṣoṣo to ni i ṣe pẹlu gbigbe oogun oloro ni wọn fi kan wọn.

Agbefọba, Ọgbẹni Sidiq Adeniyi, ṣalaye pe awọn ọdaran mẹtẹẹta naa ni wọn ṣẹ ẹṣẹ yii lọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ni deede aago meje alẹ, ni adugbo Ekute, l’Ado-Ekiti.

O sọ pe odidi apo kan to kun fun igbo ni wọn ka ma wọn lọwọ.

Ẹsẹ ti wọn n jẹjọ rẹ ọhun lo juwe gẹgẹ bii eyi to lodi sofin gbigbe egboogi oloro to jẹ ofin orilẹ-ede Naijiria ti wọn kọ lodun 2009.

O waa tọrọ aaye lọwọ ile-ẹjọ pe ki wọn sun igbẹjọ naa siwaju ki oun le raaye ko awọn ẹlẹrii oun jọ. O sọ pe oun ṣetan lati ṣe ẹjọ naa debi to lapẹẹrẹ, ati lati ri i pe awọn ọdaran metẹẹta naa ṣẹwọn.

Ṣugbọn awọn ọdaran ọhun lawọn ko jẹbi esun ti wọn fi kan awọn.

Bakan naa ni Agbẹjọro wọn, Ọgbẹni Olawumi Olowolafẹ, bẹ ile-ẹjọ pe ko fun awọn onibaara oun ni beeli, pẹlu ileri pe wọn ko ni i sa lọ.

Onidaajọ Dolapọ Babalogbọn fun awọn ọdaran naa ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ati oniduuro meji. Lẹyin eyi lo sun

Bakan naa sun igbẹjọ miiran si ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Leave a Reply