Ọgba ẹwon to wa n’Ile-Ifẹ, nipinle Ọṣun, ni adajọ ileẹjọ Magisireeti kan, Onidaajọ Kikẹlọmọ Adebayọ, ni ki wọn lọọ ju Ogbẹni Ọladipupọ Babatunde, ẹni ọgbọn ọdun, to fipa ba ọmobinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun (17) kan ti wọn ko fẹẹ darukọ lo pọ.
Ọlọpaa olupẹjọ, Insipẹkitọ Sunday Osanyintuyi, to foju Ọladipupọ bale-ẹjọ naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, sọ pe Ọladipupọ huwa ọdaju naa lọjọ Kin-in-ni, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni nnkan bii ago meji ọsan, lakooko tawọn mejeeji ti wọn jẹ oṣiṣẹ nileeṣẹ kan ti wọn ti n sin adiẹ lagbegbe naa wa papọ, ti ko si sẹnikankan nitosi wọn.
Oriṣii ẹsun meji ọtọọtọ ni Sunday fi kan Ọladipupọ, eyi to sọ pe ijiya nla wa fun ẹni to ba hu iru iwa bẹẹ labe ofin ipinlẹ Ọṣun.
Ẹsun akọkọ ni pe o ni Ọladipupọ fipa ba omidan kan sun lọna aitọ. Ẹsun keji ni pe ofin faujro si iwa ti Ọladipupọ hu yii.
Olupẹjọ sọ pe, ‘ Iwọ Ọladipupọ to jẹ osiṣẹ ileeṣẹ kan ti wọn ti n ṣin adiẹ fipa ba omidan kan ti ẹyin mejeeji jọ jẹ oṣiṣẹ nileeṣẹ kan naa lajọṣepọ. Ohun to o ṣe ni pe o lo agbara pe ọkunrin ni ẹ fun un, to o si fipa ba a sun daadaa. Inu ọmidan naa ko dun rara nitori pe ohun to o ṣe pẹlu rẹ yii ko wa lati inu ọkan rẹ. Ofin ipinlẹ Ọṣun ati ti orileede wa Naijiria faju ro si i, ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ,
Ninu ọrọ tiẹ, Ọladipupọ ti ko gba looya lati ṣoju rẹ nileẹjọ gba pe loootọ loun jẹbi awọn ẹsun ti wọn ka s’oun lẹsẹ naa, to si rawọ ẹbẹ si Onidaajọ Kikiẹlọmọ Adabayọ pe ko ṣiju aanu wo oun lori ẹjọ yii.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ ileẹjọ naa sọ pe ki wọn lọọ gba imọran wa lati ọdọ ẹka ijọba kan to n gba kootu nimọran lori aọn ẹjọ to ba jẹ mọ bayii ’Director Of Public Prosecution’ (DPP).
Lẹyin eyi lo paṣẹ pe ki wọn ju Ọladipupọ sẹwọn kan to wa n’Ile-Ifẹ titi dọjọ karun-un, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii, ti igbẹjọ yoo fi waye lori ẹjọ rẹ.