Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Apo irẹsi ọgọrun-un ni wọn ni Oyetoro Ọmọlade gba lọwọ Alhaja Eluwọle Sẹrifat lọja tuntun Odo-Ogbe, niluu Ileefẹ, lai sanwo, idi niyi to fi dero ile-ẹjọ Majisreeti lọsẹ to kọja.
Nnkan bii aago kan ọsan ọjọ kẹwaa, oṣu kẹfa, ọdun yii, ni Ọmọlade, ẹni ọdun mẹtalelogoji, lọọ gba irẹsi naa, eleyii ti owo rẹ le ni miliọnu meji naira (#2,050,000.00).
Gẹgẹ bi agbefọba to n ṣe ẹjọ naa ṣe sọ, adehun ọjọ marun-un pere lo wa laarin Ọmọlade ati Alhaja Eluwọle pe yoo fi sanwo irẹsi yii, ṣugbọn ṣe ni olujẹjọ kuna lati mu adehun aarin wọn ṣẹ.
O ni ṣe lo sọ owo irẹsi yẹn di tiẹ, eleyii to nijiya labẹ ipin irinwo o din mẹtadindinlogun (383) ati okoolenirinwo o din ẹyọ kan (419) abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.
Lẹyin ti olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun meji ti wọn fi kan an ni agbẹjọro rẹ, Ademọla Adeyẹmọ, rọ ile-ẹjọ lati fun un ni beeli pẹlu irọrun.
Ninu idajọ rẹ, Majisreeti A.A. Ayẹni faaye beeli silẹ fun olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira ati oniduuro meji ni iye kan naa. Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.
Ninu iroyin mi-in, awọn ọlọpaa ti wọ ọmọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Felix Iyokegh, lọ si kootu, ọjọ kẹtala, oṣu kẹjọ, ọdun yii, lo ji owo ni otẹẹli to ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bii manija.
Agbefọba to n ṣe ẹjọ naa, Inspẹkitọ Emmanuel Abdullahi, ṣalaye fun kootu pe ṣe ni wọn gba Felix gẹgẹ bii manija nileetura ACJAP Guest House, to wa lagbegbe Mokuro, niluu Ileefẹ.
Ṣugbọn ṣe lo ji ẹgbẹrun lọna aadoje naira (#130,000) to jẹ ti Ọgbẹni Taiwo Awoṣeemọ lọjọ naa, eleyii to nijiya labẹ ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun n lo. Agbẹjọro rẹ, Barisita Okoh Wonder, ṣeleri pe ti ile-ẹjọ ba le fun un ni beeli, yoo fi awọn oniduuro ti wọn lorukọ silẹ, bẹẹ ni ko ni i sa lọ fun igbẹjọ.
Majisreeti A. A. Ayẹni fun Felix ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira ati oniduuro meji ni iye kan naa. Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.