Faith Adebọla, Eko
Ọdọmọkunrin kan ti wọn porukọ ẹ ni Quadri Raji Arẹmu, ti ko ara ẹ si ijangbọn l’Ekoo, wahala naa ki i si ṣe kekere rara, tori ọran nla lo da, niṣe lo lọrọ kan ṣe bii ere bii awada dija laarin oun ati ọrẹ ẹ kan to n jẹ Qudus, afi bi Quadri ṣe ki ọbẹ mọlẹ, lo ba gun ọrẹ ẹ yii pa, amọ ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ti to o, wọn ti gbe e janto re teṣan wọn, o si ti n ṣẹju pako lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ, nibi ti wọn ti n fi ibeere po o nifun pọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe adugbo Idi-Aba, lagbegbe Jakande, l’Ekoo, niṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọhun. Ohun ta a gbọ ni pe ọrọ ti ko to nnkan lo ṣẹlẹ laarin oloogbe naa ati afurasi apaayan yii, wọn ni wọn jọọ n ṣe fa-n-fa lori ọrọ kan ni, afi bọrọ naa ṣe yi biri, to di ija laarin awọn mejeeji nibudokọ Idi-Aba naa.
Oloogbe Qudus ni wọn lo kọkọ fi nnkan kan gun Quadri nibi ọwọ rẹ, lẹjẹ ba bẹrẹ si i da lara ẹ. Bi Qudus ṣe ṣe Quadri leṣe yii lo mu ki ibinu rẹ ru soke, lo ba fa ọbẹ yọ, o loun maa gbẹsan dandan, o ni oloogbe naa ti gbẹjẹ lara oun, oun naa si maa gbẹjẹ lara ẹ. Amọ ṣe wọn ni oro akọda ko da bii adagbẹyin, apa ni Qudus ti gun Quadri, ṣugbọn niṣe ni Quadri ki ọbẹ ẹsan tiẹ bọ Qudus loju, ọwọ ti oloogbe naa tun gbe soke bo ṣe pariwo yee, Quadri tun fibinu ki ọbẹ ọhun bọ ọ labiya ati apa, o si ṣe leṣe yannayanna, lẹjẹ ba bẹrẹ si i ṣan bii omi.
Nigba tawọn to wa nitosi tọrọ yii ṣoju wọn yoo fi ṣugbaa Qudus, ti wọn sare gbe e digbadigba lọ sileewosan, aṣọ o b’Ọmọyẹ mọ, Ọmọyẹ ti rinhooho wọja, ọmọkunrin naa ti sọda sodikeji.
Kia lawọn bọisi ti ki Quadri mọlẹ, wọn lo gbọdọ gbe ẹran nla to pa yii ni o, n ni wọn ba pe awọn ọlọpaa.
Ṣa wọn ti gbe oku Qudus lọ si mọṣuari ileewosan IDH General Hospital, to wa ni Yaba, ibẹ ni wọn ṣe oku ẹ lọjọ si fun ayẹwo ati iwadii.
Awọn ọlọpaa si ti fi pampẹ ofin gbe Quadri lọ si teṣan wọn, o ti n ran wọn lọwọ lẹnu iwadii ti wọn n ṣe.