Faith Adebọla, Eko
Lẹyin ọdun meji aabọ tigbẹjọ fi waye, ile-ẹjọ ti dajọ ẹwọn fun ọdaran ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Joshua Usulor. Ọdun mejidinlọgbọn gbako ni yoo ṣe ni keremọnje, latari bo ṣe jẹbi ẹsun ṣiṣeku pa Abilekọ Feyiṣayọ Obot, agbejọro kan niluu Eko.
Ọwurọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni idajọ waye lori awọn ẹsun ti wọn fi kan olujẹjọ naa nile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun akanṣe ati iwa ọdaran abẹle, eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, l’Ekoo.
Ṣaaju ni Agbefọba, Abilekọ O. A. Bajulaiye-Bishi, ti ṣalaye biṣẹlẹ aburu naa ṣe waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu ki-in-ni, ọdun 2019. O ni iwadii fihan pe owo ati awọn nnkan ẹṣọ oloogbe agbejọro yii l’ọdaran naa fẹẹ ji lọjọ naa to fi yọ wọnu yara ti oloogbe ọhun haaya ninu otẹẹli kan ti wọn forukọ bo laṣiiri.
Nigba ti obinrin naa taji lojiji lawọn mejeeji wọya ija, wọn lọkunrin ọdaran yii bo oloogbe naa lẹnu tori ko fẹ ko pariwo ole le oun lori, nibẹ lo ti gun un lọbẹ nikun, o si tun ge e lọfun.
Wọn ni nigba to ri i pe Feyiṣayọ ti ku ni Joshua ko ẹgbẹrun mẹrindinlọgbọn naira ati awọn goolu oloogbe, lo ba fẹsẹ fẹ ẹ.
Agbefọba ni lasiko iwadii, Joshua jẹwọ pe loootọ loun huwa ika naa, o ni oun ko kọkọ ni in lọkan lati pa a, ṣugbọn nigba tobinrin naa fẹẹ maa pariwo le oun lori lo mu koun fi ọbẹ aṣooro kan tọwọ oun ba gun un, to si yọri si iku.
Ẹsun apaayan ati idigunjale ni wọn fi kan ọdaran yii ni kootu, eyi ti wọn lo ta ko isọri okoolerugba ati mẹta (223) iwe ofin iwa ọdaran tipinlẹ Eko.
Lẹyin tọkunrin naa ti gba pe oun jẹbi awọn ẹsun yii ni agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Spurgeon Ataene, rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ pe ki wọn ṣiju aanu wo onibaara oun, pe igba akọkọ iṣẹlẹ naa leyi, ati pe ọkunrin naa niyawo, o si ti bimọ, o ni ki wọn ma ṣe idajọ rẹ ni ẹwọn fọpawọn, ki iṣoro ati gbọ bukaata ma lọọ pa awọn mọlẹbi lori.
Adajọ Oluwatoyin Taiwo sọ pe oun ti gbọ ẹbẹ ojujẹjọ, o ni ẹwọn ọgbọn ọdun tabi ju bẹẹ lọ loun iba wọn fun ọdaran yii, ṣugbọn nitori ẹbẹ rẹ, idajọ oun ni pe ko lọọ faṣọ penpe roko ọba fun ọdun mejidinlọgbọn gbako, ki eyi le jẹ arikọgbọn fawọn ẹlomi-in.