Monisọla Saka
Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Ijọra Badia, nipinlẹ Eko, ti fi panpẹ ofin gbe awọn afurasi ọdaran mẹrin kan ti wọn n da awọn eeyan agbegbe naa laamu. Wọn ni iṣẹ tawọn ẹni ibi yii yan laayo ni ki wọn ji mọto, ki wọn si tu u ta.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ọlọpaa Eko, Benjamin Hundenyin, ṣe sọ, awọn afurasi mẹrẹẹrin ọhun, Alafia Afiwajuomo, Ganiyu Tajudeen, Ọlamilekan Hassan, ati Lucky Esomojumi, lọwọ palaba wọn segi lasiko tọwọ awọn ọlọpaa tẹ wọn labẹ biriiji Iganmu, lagbegbe Orile, nipinlẹ Eko.
Hundenyin ni, ileeṣẹ ọlọpaa lo gbe awọn ikọ onitọpinpin kan dide lati wa awọn ọdaran ti wọn n da omi alaafia agbegbe naa ru lẹyin ti arabinrin kan to n jẹ Sandra waa fẹjọ sun ni teṣan to wa ni agbegbe Ijọra pe wọn fibọn gba ọkọ Toyota Camry kan lọwọ oun lagbegbe Iganmu, Surulere nipinlẹ Eko.
“Nibi ti wọn ti n mura lati tu ọkọ naa wẹlẹwẹlẹ, ki wọn le maa tu u ta lẹyọ-kọọkan bii iṣe wọn lawọn ọlọpaa ka wọn mọ, ti wọn gba a pada.
Bakan naa ni wọn tun ri awọn ẹya ara ọkọ ti wọn ti tu silẹ tẹlẹ, ti wọn si ti ta nibẹ gba pada”.
Alukoro ọlọpaa fi kun un pe awọn ti foju awọn ọdaran naa bale-ẹjọ.