Eyi laṣiiri ohun to faja laarin Portable ati Verydarkman

 Ija buruku lo n l laarin mkunrin olorin ti ẹnu ki i sin lara rẹ nni, Habeeb Okikila, ti gbogbo eeyan m si Portable ati mkunrin to maa n sr lori ayelujara nni, Verydarkman. Nibi tọrọ naa si le de, awọn mejeeji ni wọn ti n leri sira wọn.

Bo tilẹ jẹ pe ọrọ ọmọkunrin kan to ti jẹ manija Portable, ṣugbọn ti wọn ti pin gaari bayii ti ọmọkunrin olorin ti wọn tun maa n pe ni Zah Zuh zeh lu nileejo Fẹla lawọn eeyan ro pe o fa ija Verydarkman ati Portable, ija abẹlẹ kan ti wa laarin awọn mejeeji.

Lọsẹ to kọja ni ọkunrin to maa n gbe awọn olorin jade ti wọn n pe ni Don Jazzy fun Verydarkman ni ọgọrun-un miliọnu Naira (100m), lati fi ṣe iranlọwọ fun un lori ẹgbẹ alaaanu kan to da silẹ.

Nigba ti ọmọkunrin naa kede owo ọhun lori ayelujara ni Portable bọ sita, to si sọ pe Don Jazzy ko ran oun lọwọ. O ni olorin ti ko ni olugbọwọ, to jẹ atapata-dide, to si waa rọwọ mu debii pe o n lọ siluu oyinbo kaakiri, wọn ko ni i ran an lọwọ. O ni alaini alaini ni oun naa, ki Don Jazzy ran oun lọwọ, ko tẹ owo fun oun naa, ko yee fi oun ṣe awokọṣe fawọn ọmọ olorin abẹ rẹ pe ṣebi wọn ri i bi Portable ti n ṣe. Ọlalọmi ni oun naa nilo iranlọwọ, ko ran oun lọwọ,

ki ọkunrin naa tẹ owo fun oun, ṣugbọn iyẹn ko da a lohun gbogbo bo ṣe n pariwo to.

Ikanra owo ti wọn fun Verydarkman wa lara Portable, ko too di pe iyẹn tun bu ẹnu atẹ lu iwa ti Ọlalọmi hu pẹlu bo ṣe na ọmọkunrin to jẹ manija rẹ tẹlẹ nile-ijo Fẹla. Niṣe ni wọn ni Portable tan ọmọkunrin naa jade nibi to wa lọ sile igbọnsẹ, lo ba fi ẹṣẹ da batani si i lara.

Fidio yii ni Dark man ri to fi sọ pe, ‘’Ṣe ohun ti Portable ṣe yii daa, ẹ wo bo ṣẹ lu ọmọọlọmọ nilukulu, niṣe lo yẹ ki ọlọpaa mu un, mo fẹ ki ọmọkunrin naa kan si mi’.

Eyi ni ọmọkunrin olorin to fẹran wahala yii gbọ to fi bẹrẹ si i halẹ mọ Darkman, to si n sọ pe oun maa lu u ni aludẹ toun ba gba a mu. Ko fi mọ bẹẹ, niṣe lo gbe igba funfun kan ati ilẹkẹ Ifa to fi sọwọ, to si n sọ nibẹ pe oju ọwọ ni wọn maa n dina mọ, wọn ki i dina mọ ẹyin ọwọ. O ni Verydarkman ko le halẹ mọ oun, ko lọọ beere oun ni ọja Babangida, niluu Abuja, wọn maa royin oun fun un.

Nigba to n ṣalaye idi to fi ba manija rẹ yii ja, o ni pẹlu bo ṣe ti kuro lọdọ oun, niṣe lo maa n lọọ fi orukọ oun gba iṣẹ nita, ti yoo si sọ pe ọdọ oun loun wa, leyii to mu ko ti gbe ọpọlọpọ owo oun lọ. Nigba toun si ri i nibi ayẹyẹ iranti Fẹla yii, oun mu un bii ole, oun si da sẹria fun un.

Ṣugbọn ọpọ eeyan lo ti n bu ẹnu atẹ lu iwa ti ọmọ Ọlalọmi hu, wọn ni bii bii ifiya jẹ ni ati lilo ofin lọwọ ara ẹni ni ọmọkunrin naa ṣe, eyi to si le ko o si wahala bi wọn ba gba a mu. Bakan naa lawọn kan n sọ pe ko yaa jokoo ara rẹ jẹẹ, ko ma gbe wahala rẹ de ọdọ Verydarkman, nitori bi iyẹn ba ba a kẹsẹ bọ ọ, afaimọ ko ma ba wọn lalejo ni Kirikiri. Titi di ba a ṣe n sọ yii laọn mejeeji si n tahun sira wọn.

Leave a Reply