Faith Adebọla
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tanmọlẹ si ọrọ kan to n ja ranyin bii ina ọyẹ nipa afurasi ọdaran ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Ṣeyi Oduyiga, to ku sahaamọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ni Eleweẹran, Abẹokuta, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla yii, eyi to mu kawọn eeya maa gbe e kiri pe niṣe lawọn ọtẹlẹmuyẹ fiya jẹ oloogbe naa doju iku, wọn lawọn agbofinro mọ-ọn-mọ da a loro ni.
Amọ ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, fi ṣọwọ s’ALAROYE lowurọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii, nipa iṣẹlẹ ọhun, o ni ootọ to wa nidii iku Oloogbe Ṣeyi ni pe ọsibitu lo ku si, lẹyin to ti ṣe ọpọ awọn afurasi ọdaran ti wọn jọ wa ninu sẹẹli tawọn fi wọn si leṣe yannayanna.
Alukoro ni lọjọ Tusidee, ọjọ kejidinlogun, lẹyin akọlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to waye niluu Ṣagamu, nijọba ibilẹ Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, ninu eyi ti wọn ti da ẹmi eeyan marun-un legbodo, awọn ọlọpaa bẹrẹ si i fimu finlẹ kaakiri ilu naa, paapaa laduugbo Atoyo, ibẹ lọwọ wọn ti ba awọn afurasi meji, Ṣeyi Samson Oduyiga, ẹni ọdun mọkandinlogoji, ati Adegoke Gbenga, awọn mejeeji si ni wọn jẹwọ lagọọ ọlọpaa pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Buccaneer ti wọn n pe ni Buka, ati ẹgbẹ okunkun Aiye lawọn. Wọn ni Ṣeyi tun jẹwọ pe ọdun 2015 loun dọmọ ẹgbẹ okunkun.
Lẹyin tawọn ọlọpaa ti pari iwadii wọn, wọn foju awọn afurasi naa bale-ẹjọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, amọ kootu akanṣe to maa n gbọ ẹjọ awọn ọmọ ẹlẹgbẹkẹgbẹ nipinlẹ Ogun, eyi to fikalẹ sagbegbe Iṣabọ, ko jokoo idajọ lọjọ naa, niṣe ni wọn ni ki wọn ko awọn afurasi naa pada wa lọjọ keji.
Lafẹmọjumọ ọjọ keji, iyẹn Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, ti wọn n palẹmọ ati ko wọn lọ, ni nnkan bii aago marun-in idaji naa, niṣe lawọn ọlọpaa ṣadeede gburoo ija ati ariwo ninu sẹẹli Eleweeran, ti rogbodiyan si ṣẹlẹ laarin awọn afurasi to wa nibẹ. Wọn ni afurasi yii, Ṣeyi Oduyiga, lo ṣadeede sọ ija nla kalẹ, to si bẹrẹ si i ṣe bii ẹhanna lojiji, niṣe lo n deyin mọ awọn afurasi yooku, to si n ge wọn jẹ yannayanna. Nigba tawọn ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ lasiko ọhun yoo fi dẹrọ wahala naa, o ti feyin da batani sawọn kan lara.
Ṣa, wọn sare gbe oun ati awọn to fara gbọgbẹ ninu rogbodiyan naa lọọ sileewosan ijọba Jẹnẹra ọsibitu Ijaye, nigboro Abẹokuta, wọn si bẹrẹ si i fun wọn nitọju pajawiri, amọ ẹnu itọju naa ni wọn wa ti Ṣeyi fi mi kanlẹ, to si dagbere faye.
Alukoro Odutọla ni wọn ti gbe oku afurasi yii lọ fun ayẹwo iṣegun lati mọ ohun to rọ lu u gan-an, bẹẹ si ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Alamutu Abiọdun Mustapha, ti kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi rẹ.
Awọn ọlọpaa ni okodoro otitọ ohun to ṣẹlẹ lawọn sọ yii, yatọ si iroyin ẹlẹjẹ to n lọ kaakiri ori ẹrọ ayelujara.