Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ko sẹni to de ayika ile-ẹjọ giga ijọba apapọ, iyẹn Federal High Court, to wa niluu Ilọrin, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ti ko ni i mọ pe igbẹjọ pataki kan n lọ lọwọ latari b’awọn ẹṣọ alaabo ṣe duro wamuwamu, ti ọkọ awọn lọọya si kun gbogbo ayika kootu naa fọfọ.
Ọjọ yii ni igbẹjọ n tẹsiwaju lori awọn ẹṣun iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku ti wọn fi kan gomina tẹlẹri nipinlẹ Kwara, Abdulfatai Ahmed, ati kọmisanna rẹ lẹka eto inawo lasiko iṣẹjọba wọn laarin ọdun 2011 si ọdun 2019, Ademọla Báànú.
Nigba ti igbẹjọ bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ẹni to jẹ igbakeji lẹka eto inawo ni ajọ UBEC (Universal Basic Education Commission), Abubakar Hassan, yọju si kootu lati jẹrii ta ko gomina tẹlẹ ọhun, Abdulfatai Ahmed, pe loootọ lo gbe biliọnu marun-un le diẹ (5.78b) to jẹ owo to wa fun eto ẹkọ kari aye yii gba oko ibomiiran lọ lasiko to n ṣejọba laaarin ọdun 2013 si 2015.
Abubakar sọ pe owo ọhun lo wa fun ṣiṣan owo awọn olukọ UBEC, ṣugbọn ti Fatai Ahmed ko owo naa sapo ara rẹ.
Agbefọba, Rotimi Jacob (SAN), to ṣoju EFCC sọ fun ile-ẹjọ pe ko fun Abubakar laaye lati ṣọrọ gẹgẹ bii ẹlẹrii lori ẹsun owo rẹpẹtẹ to dawati lasiko iṣejọba gomina tẹlẹri ọhun.
Lẹyin ti ẹlẹrii gunlẹ ọrọ rẹ ni Onidaajọ Muhamud Abdulgafar, sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji, ọdun 2025, gẹgẹ bii ọjọ ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.
Tẹ o ba gbagbe, o ti ṣẹ diẹ ti igbẹjọ ti n lọ lori ẹsun ti wọn fi kan gomina tẹlẹ ọhun ti wọn ni oun ati kọmiṣanna rẹ ko owo bantabanta jẹ. Ileeṣẹ to n ri si iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ wa (EFCC), lo mu awọn eeyan yii, latigba naa ni wọn ti n ba wọn ṣẹjọ.