Ni orilẹ-ede Naijiria tiwa loni-in yii, o fẹrẹ ma si ọdun kan ti awọn olukọ yunifasiti ko ni i da iṣẹ silẹ, bi won ba si ti daṣẹ silẹ bẹẹ, gbogbo yunifasiti ni wọn yoo ti pa, awọn akẹkọọ ko ni i lọ si ile-ẹkọ, ohun gbogbo yoo si ri rudurudu. Bi ọrọ ba si ti ṣẹlẹ bayii, ijọba yoo ni awọn olukọ yunifasiti yii ni alaṣeju, awọn olukọ paapaa yoo si ni ijọba Naijiria ni aṣadehun-maa-mu-un-ṣẹ, awọn ni wọn ki tẹ le adehun ti won ba ṣe.
Ṣugbọn bi erin meji ba n ja ninu igbo lọrọ yii, awọn koriko ibẹ ni yoo fara pa ju lọ. Bi ijọba apapọ ati ẹgbẹ awọn olukọni ni yunifasiti ba n ja, awọn ọmọleewe, ati eto-ẹkọ ni Naijiria ni yoo fara pa. Bi nnkan si ti ṣe ri ni ilẹ wa bayii ree, nigba to jẹ ọdọọdun ni ija awọn mejeeji n waye. Eto ẹkọ ko lọ deede, ẹkọ ti awọn ọmọ wa si n kọ paapaa ko ye kooro to.
Ki waa lo maa n faja awọn eeyan yii lojoojumọ bẹẹ? Ohun ti Alaga Ẹgbẹ awọn olukọni ni yunifastii gbogbo, Ọjọgbọn Abiọdun Ogunyẹmi, yoo fi bii wakati meji ṣalaye niyi lati aago mẹrin irọlẹ oni, Ọjo Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kẹrin, 2021. Bo ba ti n sọrọ naa ni yoo maa gori afẹfẹ lesẹkẹsẹ, gbogbo eeyan yoo maa gbọ ọ ti wọn yoo si maa wo o lori Alaroye Online Television.
Ileeṣẹ awọn ọjọgbọn Amẹrika kan, Toyin Falọla Interviews, lo gbe eto naa kalẹ, ti Alaroye si jẹ ọkan ninu awọn abanidowopọ wọn. Bo tilẹ je pe ede oyinbo ni wọn yoo fi ṣeto naa, gbogbo eeyan lo le gbọ ọ nitori awọn oyinbo ti ko ni i le pupọ ni, ati pe bo ba ya, Alaroye yoo tumọ ifọrowanilẹnuwo yii si Yoruba seti gbogbo aye.
Ẹ pade wa ni aago mẹrin irọle yii ni Facebook tabi YouTube, ki ẹyin naa le kọ imọ kun imọ, ki ẹ si fi akoko naa mọ ohun gbogbo to ba n lọ nipa eto ẹkọ wa ni Naijiria.