Eyi lawọn ti yoo janfaani bi mo ṣe wọle lẹlẹẹkeji ju lọ- Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti fi awọn ọdọ lọkan balẹ pe wiwọle ti oun wọle idibo fun saa keji nipo gomina yii yoo ṣi ọna aṣeyọri fun wọn.

Nibi ariya ti wọn ṣe lati ṣajọyọ bi Gomina Makinde ṣe wọle idibo fun saa keji lo ti sọrọ naa nileegbafẹ Ilaji Hotel and Resort, to wa laduugbo Akanran, n’Ibadan, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Aparo kan ko ga ju ọkan lọ mọ nipinlẹ Ọyọ lọwọ ta a wa yii, awọn aparo ti wọn gori ebe lati fi han gbogbo aye pe awọn ga ju ara yooku lọ, emi Ṣeyi Makinde ti fi oko nla le wọn kuro lori ebe, bakan naa ni gbogbo wa ri bayii.

O kan saara si oludasilẹ ileegbafẹ naa, Ẹnjinnia  Dọtun Sanusi, fun ipa to ko ninu idibo to gbe e wọle. Bẹẹ lo dupẹ lọwọ awọn ẹlẹsinjẹsin gbogbo fun atilẹyin ti wọn ṣe fun un lasiko idibo naa lai fi ti ẹsin ṣe.

Bakan naa lo fi awọn ti ko dibo fun un lọkan balẹ pe oun ko ni i ranro, koda oun ti ṣetan lati gba wọn mọra ninu iṣejọba oun.

Lara awọn to peju sibi ayẹyẹ ọhun ni adari ẹgbẹ awọn omolẹyin Jesu (CAN), awọn Musulumi, ẹgbẹ awọn ontaja, ẹlẹsin ibilẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Leave a Reply