Adewale Adeoye
Ni agbegbe kan ti wọn n pe ni Shola Quarters, niluu Katsina, nibi ti eto aisun alẹ igbeyawo ti n lọ lọwọ, ni ajọ to n gbogun ti lilo ati gbigbe oogun oloro nilẹ wa, (NDLEA), ti ya bo awọn ọdọ ti wọn kora wọn jọ fun aisun alẹ igbeyawo, ti wọn si mu ọkọ iyawo atawọn ọrẹ rẹ bii mẹẹẹdọgbọn lọ.
Eyi ko sẹyin bi wọn ṣe ni ọkọ iyawo naa, Musa Ghandi, ṣe ko awọn ọrẹ rẹ jọ, ti wọn si n ṣ idije oogun oloro mimu. ALAROYE gbọ pe o fẹrẹ ma si oogun oloro ti ko pe tan si ibi ti awọnb eeyan naa wa, ti wọn si n mu un bii ẹni mu omi, bẹẹ ni wọn fi n ṣe idije ti wọn fẹẹ mọ ẹni to le mu un ju ara wọn lọ.
Lẹnu eleyii ni wọn wa ti awọn kan fi lọọ ta ileeṣẹ to n gbogun ti oogun oloro lilo nilẹ wa, NDLEA lolobo lori igbesẹ buruku ti wọn n gbe ọhun. Loju-ẹsẹ ni awọn eeyan naa si ti ya lọ sibẹ. Niṣe lọrọ si di bo o lọ o yago nigba tawọn ọdọ naa ri awọn agbofinro yii, onikaluku fẹsẹ fẹ ẹ, ṣugbọn ọwọ pada tẹ bii mẹẹẹdọgbọn ninu awọn eeyan naa, ti wọn si ṣu wọn rugudu, ni wọn ba ko wọn sọ si mọto, wọn gbe wọn lọ. Titi di ba a si ṣe n sọ yii, ọdọ awọn ajọ to n gbogun ti gbigbe ati lilo egboogi oloro nilẹ wa, iyẹn ajọ ‘National Drug Law Enforcement Agency NDLEA, ẹka tipinlẹ Katsina, ni awọn eeyan naa wa, ti wọn n ran wọn lọwọ lori iwadii ti wọn n ṣe nipa gbigbe egboogi oloro ti wọn fi kan wọn.
ALAROYE gbọ pe aipẹ yii ni Ọgbẹni Musa pe awọn ọrẹ rẹ jọ fun ti ayẹyẹ inawo igbeyawo rẹ. Oniruuru egboogi oloro, eyi tawọn alaṣẹ ilu ti kede pe ko da fawọn ọdọ ilu lati maa lo ni wọn pese sibi ayẹyẹ inawo ọhun, ti gbogbo awọn ọdọ to wa sibi ayẹyẹ naa si n mu awọn egboogi ọhun ni amupara.
Ko pẹ tawọn ajọ NDLEA yii gbọ nipa ohun to n ṣẹlẹ yii ni wọn ti lọọ f’ọwọ ofin mu gbogbo wọn pata. Awọn ọrẹ ọkọ iyawo mẹẹẹdọgbọn ni wọn gba mu, ti wọn si ju gbogbo wọn si ahaamọ titi di ba a ṣe n sọ yii.
Atẹjade kan ti Alukoro ajọ NDLEA yii, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, fi sita niluu Abuja, ti i ṣe olu ilu ilẹ wa lọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii, lo ti sọ pe awọn ti pada lọọ fọwọ ofin mu ọkọ iyawo ọhun nibi to sa lọ, ati pe awọn maa ba a ṣẹjọ laipẹ yii, nitori pe oun gan-an lo ṣeto inawo ọhun, ati pe egboogi oloro ti wọn ba lọwọ awọn alejo rẹ ni ode naa ko daa rara, ti ofin ilẹ yii si fajuro gidi si patapata